Friday, March 29, 2019

Òkànràn Méjì




Òkànràn Méjì A
Ifá pé owó eléyìun ó ba ire. Owóo rè ó tòó nnkan ti n lé ti ò bá, sùgbón kó rúbo. Gbogbo ebo ò gbodò tàsé.

Òkànràn kan níhìín
Òkànràn kan lóhùún
Òkànràn di Méjì o se ìdí jàwàlá
A díá fún Jìngbìnní
Èyí ti n lo rèé fowo araa rèé bèso
Owó òun le te ire?
Wón ní kó rúbo
Ó sì gbébo nbè
Ó rúbo
Owóo rè tó tutù
Owóo rè tó ajé
Òkànràn kan níhìín
Òkànràn kan lóhùún
Òkànràn di Méjì o se ìdí jàwàlá
A díá fún Jìngbìnní
Èyí ti n lo rèé fowo araa rèé bèso
Jìngbìnní mòmò dé o awoo re
Owó mi tó tutù jé ó bàjé
Jìngbìnní dé ò awoo re
Owó tó tutù jé ó bajé

Òkànràn Méjì A
Ifá dice que esta persona obtendría todas las fortunas que él había estado siguiendo. Pero le aconsejan que realice sacrificio. Él no debe reducir su sacrificio.

Un Òkànràn localizó aquí
Otro Òkànràn localizó allí
Òkànràn se vuelve dos, mientras teniendo la base lánguida
Adivinación lanzada para Jìngbìnní
El que iba a cosechar las fortunas con sus manos
'Mi mano conseguiría a las fortunas? Ella preguntó
Ellos le dijeron que realizara sacrificio
Ella oyó hablar del sacrificio
Y lo realizó
La mano que no había estado lleno de riqueza
Ella se hizo inmensamente rica
Ella dijo que Un Òkànràn localizó aquí
Otro Òkànràn localizó allí
Òkànràn se vuelve dos y con la base lánguida
Adivinación lanzada para Jìngbìnní
El que iba a segar las fortunas con sus manos
Jìngbìnní esta realmente aquí el sacerdote bueno
Permita mi mano que está fría tocar fortunas
Jìngbìnní está aquí el sacerdote bueno
Permita la mano que está fría tocar fortunas.

Òkànràn Méjì B

Bélébo ò bá peni
Àsèfín won ò yeni
Òrò temí ò se wò
Kolombo ni n ó sojú
A díá fún Èjì Òkànràn
Níjo ti n re ilé Ètilè
Wón ní ó rúbo
Kó lè baà tètè sérí wálé
Ó wáá gbébo nbè
Ó rúbo
Ó dÉtilè lo domo
Ìgbà tóó dÉdtilè loò féléé wá mó
O dÉtilè lo domo

Òkànràn Méjì B

Si uno que requiere sacrificio no hace llamado en uno
El problema de tener que realizar un sacrificio competente no es necesario
El caso en que yo no compartí
Mi cara no traicionaría ninguna ansiedad
Adivinación lanzada para Èjì Òkànràn
En el día él iba a Ilé Ètilè
Le pidieron que realizara sacrificio
Tal que él devolvería rápidamente a casa
Él oyó hablar del sacrificio
Y lo realizó
Usted llegó Ètilè y se vuelve un niño que vale la pena
Era cuando usted llegó Ètilè que usted no quiso devolver casa de nuevo
Usted llegó Ètilè y se vuelve un niño que vale la pena.

Òkànràn Ogbè A
Ogbè pé ire fún eléyìun; Yóó dáa fún un, ara ó rò ó, ebo ni kó rú.

Kèèròmí Awo Ológun Ìsesè
Ló díá fún Ológun Ìsesè
Èyí tíí sawo èbá ònà
Ará le ro òun báyìí?
Wón ní kí Ológun ìsesè ó rúbo
Wón ní bí ará ó ti ròó tó
Kò níí seé fenu so
Ìyà ni Ológun Ìsesè sì tí n jeé bò
Ológun Ìsesè bá rúbo
Ó bá là
Òun náà?
N ní wá n jó ní wá n yò
Ní n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Kèèròmí Awo Ológun Ìsesè
Ló díá fún Ológun Ìsesè
Èyí tíí sawo èbá ònà
Kèè tíì rò mí ò omo Awo
Ifá bó bá rò mí tán
N ó fi Ihun dádè
Kèè tíì ró mí ò omo Awo

Òkànràn Ogbè A
Ifá desea bien a esta persona. La vida sería fácil para él; pero debe ofrecer sacrificio.

Kèèròmí el sacerdote de Ológun Ìsesè
Adivinación lanzada para Ológun Ìsesè
Ológun Ìsesè el sacerdote de la orilla del camino
'La vida sería en absoluto fácil para mí'? Él había preguntado
Ellos le dijeron que ofreciera el sacrificio
Y que la facilidad que él encontraría en la vida
Él se sorprendería
Ológun Ìsesè había estado teniendo los tiempos duros
Él realizó el sacrificio entonces
Él se hizo rico
¿Y sorprendido, él exclamó 'yo?'
Él empezó a bailar y regocijar entonces
Él estaba alabando su Babaláwo
Su Babaláwo estaba alabando Ifá
Él dijo que era exactamente como su Babaláwo había dicho
Kèèròmí el sacerdote de Ológun Ìsesè
Adivinación lanzada para Ológun Ìsesè
Ológun Ìsespe es el sacerdote de la orilla del camino
No es en la actualidad demasiado fácil para mí
Ifá, si se pone fácil para mí
Yo usaré una cuenta de Iyù para marcar el fin de mi Idè
No es en la actualidad demasiado fácil para mí.

Òkànràn Ogbè B
Ire; ayé ó ye é. Ifá pé kí eléyìun ó móo se bíi toko è Ayé ó ye oko è.

Asèsè rú ewé ògúnsèrè
Won a máa wu Eléko tìígí
Títí alé
Títí alé a máa sapá kaka sólóriri
Adia fún Jìngbìnní tíí saya Òrúnmìlà
Wón ní kó móo se bíi tifá
Ayé ye Jìngbìnní
N ní wá n jó ní wá n yò
Ní n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Asèsè rú ewé ògúnsèrè
Won a máa wu Eléko tìígí
Títí alé a máa sapá kaka sólóriri
Adia fún Jìngbìnní tíí saya Òrúnmìlà
Jìngbìnní dé ò aya Awo
Awó tó sì gbó Ifá a gbé idè borùn
Jíngbìnní dé ò aya Awo
Jìngbìnní deni olà láye

Òkànràn Ogbè B
Ifá dice que la vida agradaría (complacer, gustar, dar gusto) a esta persona. Ifá le pide que se comporte como su marido. La vida la agradaría así como a su marido.

Como frescamente las hojas crecientes de ògúnsèrè
Ellos incitan un Eléko permanentemente
Cultive su madurez
Cultive su madurez que ellos se comportan arrogantemente a un Olóriri
Adivinación lanzada para Jìnbìnní la esposa de Òrúnmìlà
Le pidieron que se comportara como Ifá
Ella hizo así y la vida la agradó así
Ella empezó a bailar y regocijar entonces
Ella estaba alabando sus Babaláwos
Sus Babaláwos estaban alabando Ifá
Ella dijo que es exactamente como sus Babaláwos dijeron
Como frescamente las hojas crecientes de ògúnsèrè
Ellos incitan un Eléko permanentemente
Cultive su madurez
Cultive su madurez que ellos se comportan arrogantemente a un Olóriri
Adivinación lanzada para Jìngbìnní, la esposa de Òrúnmìlà
Un Babaláwo sabio se pondría un collar del idè
Jìngbìnní está aquí la esposa de un sacerdote
Jìngbìnní se vuelve una persona rica en la tierra.



Òkànràn Òyèkú A
Ire fún eléyìun. Ojo tí ón bá yan ebo fún eléyìun ni kó rúbo òhún. Ifá pé eléyìun ní ègbón kan: òun ní ó tùún ti ègbón òhún se.

Rúwá n yáá só; Rúwá n yáá só
Rúwá n sánmò; Rúwá n sánmò
Omí yáá rúbo
Àì jeun sùn yáá wí
Ebo ká fowó bo enu
Ká fé e nù
Ó yá n rúrú
A díá fún Olòkànràn
Èyí tí n lo rèé ye iké orí ègbón è
Wón ní kó rúbo
Wón ní Ajogún kan n be lórùn ègbón è
Àbúrò è ní ó sì fàá yo
Olòkànràn bá rúbo
Ègbón è náà rúbo
Ayé ye wón
N ní wón wá n jó ní wón n yò
Ní wón n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Won ní béè làwon Babaláwo tàwón wí
Rúwá n yáá só; Rúwá n yáá só
Rúwá n sánmò; Rúwá n sánmò
Omí yáá rúbo
Àì jeun sùn yáá wí
Ebo ká fowó bo enu
Ká fé e nù
Ó yá n rúú
A díá fún Olòkànràn
Èyí tí n lo rèé ye ikú orí ègbón è
Ebo n wón ní ó sé
Olòkànràn gbébo nbè
Ó rúbo
Kín ló ye ikú orí egbon lo?
Olòkànràn
Ló ye ikú orí egbon lo
Olòkànràn.

Òkànràn Òyèkù A
Ifá desea bien a esta persona. El él o ella debe realizar sacrificio prescrito el mismo día. Él tiene un hermano; él es el que remendaría la vida del hermano.

Rúwá n yáá só
Rúwá n sánmo
El agua es rápida hacer uso de como un sacrificio
Acostándose rápidamente sin la comida será recontado
El sacrificio de poner una mano en la boca
Y soplando fuera
Es rápido realizándolo
Adivinación lanzada para Olòkànràn
El que iba a quitar el hechizo de muerte en el cuello de su hermano
Le pidieron que realizara sacrificio
Ellos le dijeron que hay un Ajogun en el cuello de su hermano
Y es el hermano menor que lo salvaría
Olòkànràn realizó el sacrificio
El hermano también realiza el suyo propio
La vida los agradó a todos
Ellos empezaron a bailar y regocijar entonces
Ellos estaban alabando sus Babaláwos
Sus Babaláwos estaban alabando Ifá
Ellos dijeron que era exactamente como su Babaláwos había dicho
Rúwá n yáá só
Rúwá n sánmo
El agua es rápida hacer uso de como un sacrificio
Acostándose rápidamente sin la comida será recontado
El sacrificio de poner una mano en la boca
Y soplando fuera
Es rápido realizándolo
Adivinación lanzada para Olòkànràn
El que iba a quitar el hechizo de muerte en el cuello de su hermano
Le pidieron que realizara sacrificio
Olòkànràn oyó hablar del sacrificio
Y lo realizó
¿Quién había quitado el hechizo de muerte en el cuello del hermano?
Olòkànràn
Es el que ha quitado el hechizo en el cuello de su hermano
Olòkànràn

Òkànràn Òyèkú B
Ifá pé kí eléyìun ó rúbo fún àwon omo è. Yóó móo jayé dáadáa.

Yabgí aborí kugú
A díá fún Olòkànràn níjó tómo rè tí n yàán kú
Wón ní ó rúbo ntorí àwon omo è
Wón ní gìrìpá òrúko lebo
Ó rúbo tán
Òjòjò ó bá se àwon omo è mó
Òjòjò ò se òun náà mo
Omo Olòkànràn bá n jayé
Ó ni béè làwon Babaláwo tòún wí
Yangí aboéi kugú
A díá fún Olòkànràn níjó tómo rè tí n yàán kú
Kómo è ó mó yàn kú mó o
Ayé làwá n je
Omo Olòkànràn ò kú mó o
Ayé làwá n je.


Òkànràn Òyèkù B
Ifá le pide a esta persona que realice el sacrificio para sus niños; él disfrutaría la vida.

Yangí aborí kugú
Adivinación lanzada para Olòkànràn, en el día que sus niños estaban muriendo en sucesiones
Un macho cabrío maduro es el sacrificio
La enfermedad no podría infligirlo de nuevo
La enfermedad no podría infligir a sus niños de nuevo
Los niños de Olòkànràn empezaron a disfrutar la vida
Él dijo que era exactamente como su Babaláwo había dicho
Yangí aborí kugú
Adivinación lanzada para Olòkànràn que fue pedido realizar sacrificio
Tal que sus niños no se morirían de nuevo en las sucesiones
Nosotros estamos disfrutando la vida
Los niños de Olòkànràn no mueran de nuevo
Nosotros estamos disfrutando la vida

Òkànràn Ìwòrì A
Ire fún eléyìun. Ifá pé ká rúbo kí enìkán ó mó gba oore wa pò mó tiè.

Òkàn kì kìì kì
Babaláwo Ojó ló díá fún Ojó
Òkàn kì kìì kì
Awo Òjò ló dáá fún Òjò
Wón ní kí wón ó rúbo
Òjò ló rúbo ju Ojó lo
Ebo ti Òjó pé pérépéré
Sùgbón ti Ojó ò pé rárá
Bó ti wù kí Ojó ó yora tó
Bí Òjò bá béè lè
Yóó pa ojú Ojó ni
Òjò wá n jó n ní n yò
N yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ni béè làwon Babaláwo tòún wí
Òkàn kì kìì kì
Babaláwo Ojó ló díá fún Ojó
A bù fún Òjò
Wón ní kí àwon méjèèjì ó sá káalè
Ebo ni kí wón se
Òjò nìkàn ní n be léyìn tó rúbo
A ní mo sebo Òkànràn kì
Kì kìì kì
Níbi Òjò bá Ojó
Níbè náà níí fi Ojó sí

Òkànràn Ìwòrì A
Ifá desea bien a esta persona. Sus cosas no estarían en desorden. Él debe ofrecer sacrificio tal que alguien no tomaría sobre de su posición legitima.

Òkàn kì kìì kì
El Babaláwo de Día lanzo adivinación para la Luz del día,
Òkàn kì kìì kì
El Babaláwo de Lluvia lanzo adivinación para la Lluvia,
Los dos de ellos fueron aconsejados realizar sacrificio
Cuando ellos realizaron su sacrificio
La lluvia ofreció su propio muy completo (lleno)
El sacrificio de Día no estaba en absoluto completo
Cualquier cosa es el brillo del día
Una vez que empieza a llover
Oscurecería el brillo del día
La lluvia empezó a bailar y regocijar entonces
Él estaba alabando su Babaláwo
Su Babaláwo estaba alabando Ifá
Él dijo que era exactamente como su Babaláwo había dicho
Òkàn kì kìì kì
El Babaláwo de Día lanzo adivinación para la Luz del día,
También lanzo adivinación para la Lluvia
Los dos les fue pedido cuidar de la tierra
Ellos deben realizar el sacrificio
Era la lluvia que viene detrás de realizar el sacrificio
Él diría que yo he realizado el sacrificio de Òkànràn kì
Kì kìì kì
Dondequiera que la lluvia se encuentra al día
Es allí que le daría alcance

Òkànràn Ìwòrì B
Ifá pé àwon méjì kan lóùn n báá wí. Kí àwon méjèèjì ó rúbo; Kí nnkan àbàadì ó mó wàá selè sí enìkan nnúu won. Ifá pé kí wón ó bi òun leeré enìkejì eléyìun tí ó rúbo se ìkejì. Ayé ó ye àwon méjèèjì.

Ma rín o kú ma sá
Ma sá o kú man rín
Yàn bílíkí o kú yàn páàsì
Ìjà àgbààgbà méjì ni ò wò
Ìjà àgbààgbà méjì n làlá Olófin
Asá ló kókó tètè sapepe lÀáfin Òyó
Wón ní kí Oba ó rú Igún
Kílé ayé ó lè baà gún
Wón ní kó rú Òsìn
Kí àwon tí ò sìn ó lè baà sìn
KÓba ó rú Tèntèré
Kílé ayé ó lè baà téjú
Nígbà ìwásè
Àwon Oba tòrun bò wálé ayé
Ilé ayé tí àwón n lo yìí dáa báyìí?
Wón bá to Òrúnmìlà lo
Òrúnmìlà níwo Oba
Ìwo nìkan lóó boríi gbogbo ènìyàn láyé
Sùgbón o ó rùú Igún o
Obá bá rú Igún
Ó á sì rú Òsìn
Obá rú Òsìn
Ó ó sì rú Tèntèré
Obá tún rú Tèntèré
Ngbà Obá dé ilé ayé
Igún tí é e rúbo
Ayé gún mó o lówó
Òun nikan ni ón mo lólórí
Àwon òtè tí ò sìn
Gbogboo won ní ón padà wáá sìn
Ngbà tí ó rùú Tèntèré
Ilé ayé bá téjú
Peresese layé lo
Wón ní Obá mò ti rú Igún
Ilé ayé mò gún ùn
Ó mòmò ti rú Òsìn
Àwon tí ò sín tí n sìn
Ó mòmò ti rú Tèntèré
Ilé ayé mo ti téjúù
Wón ní taa le rí pèlú è
Wón ní àwón rí Akódá
Wón ní àwón rí Asèdá
Wón ní àwón rí Olúwo
Àwon sì rí Odùgbònà
Àwon tún rí Àgbongbòn
Wón ní gbogbo Ìjòyé ti pé
N ní wá n jó ní wá n yò
Ní n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Ma rín o kú ma sá
Ma sá o kú ma rín
Yàn bílíkí o kú yàn páàsì
Ìjà àgbààgbà méjì ni ò wò
Ìjà àgbààgbà méjì n làlá Olófin
Asá ló kókó tètè sapepe lÁàfin Òyó
Wón ní kí Oba ó rú Igún
Kílé ayé ó lè baà gún
Oba rú Igún
Ilé ayé bá gún
Wón ní kó rú Òsìn
Kí àwon tí ò sìn ó lè baà sìn
Oba rú Òsìn
Gbogbo àwon tí ò sìn ní n sìn
KÓba ó rú Tèntèré
Kílé ayé ó lè baà téjú
Oba rú Tèntèré
Ilé ayé sì Téjú
Obá gbó gbogbo ebo
Obá bá rúbo
Ó ní m orí Akódá
Mo rí Asèdá
Mo rí Olúwo
Mo sì rí Odùgbònà
Ìgbà táa rí Àgbongbòn
Awó pé

Òkànràn Ìwòrì A
Ifá dice que él está refiriéndose a un grupo de dos personas. Que los dos deben realizar sacrificio tal que una casualidad mala no pasaría inesperadamente a uno de ellos. Ifá manda a esta persona para preguntar quién es la segunda persona. La vida los agradaría a ambos.

Ma rín o kú ma sá
Ma sá o kú ma rín
Yàn bílíkí o kú yànpáàsì
Es la lucha de dos superiores que son indeseables
La lucha de dos superiores es la pesadilla de Olófin
La Cometa fue el primero en ser exuberante en el palacio del rey de Òyó
Ellos le dijeron al Rey que sacrificara el pájaro de Igún
Tal que el mundo se arreglara (colocaría, ordenara) bien
Ellos le dijeron que sacrificara el pájaro de Òsìn
Tal que aquéllos que se negaron rendir culto le rendirían culto
Ellos le dijeron al Rey que sacrificara el pájaro de Tèntèré
Tal que la tierra sería llana (plana, aplastada, sin brillo) y extensa
En los días antiguos
Los Reyes estaban viniendo del cielo a la tierra
'¿Habría la tierra que nosotros vamos ser en absoluto buena '?
Ellos fueron a consultar Òrúnmìlà
'Ustedes los Reyes ', Òrúnmìlà dijo
'Ustedes solo prevalecerían en todas las personas en la tierra '
'Pero ustedes debe sacrificar un pájaro de Igún '
'Los Reyes sacrificaron el pájaro de Igún '
'Ustedes también sacrificarán un pájaro de Òsìn '
Los reyes ofrecieron el pájaro de Òsìn
'Ustedes también sacrificarán el pájaro de Tèntèré ', Òrúnmìlà dijo concluyentemente
Ellos ofrecieron el pájaro de Tèntèré
Cuando los Reyes llegaron a la tierra
El pájaro de Igún que ellos habían sacrificado
La vida se puso en orden bien para ellos
Él es un único conocido o consideró como la cabeza
El rebelde que se había negado a rendirle culto
Todos ellos regresaron a rendirse culto
Cuando él sacrificó el pájaro de Tèntèré
El mundo se volvió extenso
La tierra se volvió muy llana
Ellos dijeron 'El Rey había ofrecido un pájaro de Igún '
El mundo se ordeno ahora bien
Él también ofreció un pájaro de Òsìn
Ésos que se habían negado a rendirle culto ahora son adoradores
Él ofreció el pájaro de Tèntèré
El mundo se volvió la extensión
'¿Quién usted vio con él '?
Ellos preguntaron
Él vio Akódá
Él vio Asèdá
Olúwo estaba allí
Así hace Odùgbònà
Nosotros también vimos Àgbongbòn, ellos dijeron
Ellos razonaron 'Todos los jefes están completos '
Ellos empezaron a bailar y regocijar entonces
Ellos estaban alabando sus Babaláwos
Sus Babaláwos estaban alabando Ifá
Ellos dijeron que era exactamente como sus Babaláwos dijeron
Ma rín o kú ma sá
Ma sá o kú ma rín
Yàn bílíkí o kú yànpáàsì
Es la lucha de dos superiores que son indeseables
La lucha de dos superiores es la pesadilla de Olófin
La Cometa fue el primero en ser exuberante en el palacio del rey de Òyó
Ellos le dijeron al Rey que sacrificara el pájaro de Igún
Tal que el mundo se arreglara bien
El rey ofreció un pájaro de Igún
Y el habría ser arreglado bien
Ellos le dijeron que sacrificara el pájaro de Òsì
Tal que aquéllos que se negaron a rendirle culto le rendirían culto
El Rey ofreció un pájaro de Òsìn
Todos aquéllos que nunca tenían adoradores empezaron a rendirles culto
Ellos le dijeron al Rey que sacrificara el pájaro de Tèntèré
Tal que la tierra sería llana y extensión
El Rey ofreció el pájaro de Tèntèré
La tierra se volvió una extensión
El Rey oyó hablar del sacrificio
Y lo realizó
'Nosotros vimos a Akódá '
'Nosotros vimos a Asèdá '
'Nosotros vimos a Olúwo '
'Nosotros vimos a Odùgbònà '
'Cuando nosotros vimos Àgbongbòn ', ellos dijeron
Todo el orden de sacerdocio está completo

Òkànràn Òdí A
Ifá pé ara eléyìun ó le. Yóó gbádùn ayé è. Emí e ó gùn sùgbón kó rúbo Òkànràn Òdí.

Òkànràn din din kúù din kúù din
A díá fún Owú
Èyí tí n sògbògbò àrùn
Tí n najú aláì le nde
Wón ní ebo ara líle ni kó rú
Owú ní n se jègèjègè lÁgbède
Wón ní kó rúbo kí ara è ó le
Wón ní wón ó jàn án jàn án
Ipá ò níí kà a
Èmí è ó sì gùn
Owú bá rúbo
Ebo è bá dà
Òkànràn din din kúù din kúù din
A díá fún Owú
Èyí tí n sògbògbò àrùn
Tí n najú aláì le nde
Wón ní ó rúbo
Owú gbébo nbè ó rúbo
Ó rúbo tán lará bá le
A ní mo ti sebo
Mo ti sebo Òkànràn dindin kúù din kúù din
Mo rúbo Òkànràn di n din kúù din kúù din
Ni Owú n wí lÁgbède

Òkànràn Òdí A
Ifá dice que esta persona estaría llena de longevidad. Él disfrutaría su vida; pero debe ofrecer sacrificio de Òkànràn Òdí.

Òkànràn dindin kúù din kúù din
Adivinación lanzada para el Molde (moho, moldura)
Que se arrestó por la enfermedad
Y visto sin poder ponerse de pie
Ellos le dijeron que ofreciera sacrificio para la buena salud
El Molde había estado previamente enfermo en la tienda del herrero
Ellos le pidieron que sacrificara para la salud buena y vitalidad
'Ellos golpearían y lo golpearían'
'Nada lo superaría'
'Usted también tendría la vida larga', ellos dijeron
El Molde realizó el sacrificio
Y su sacrificio fue aceptado
Òkànràn din din kúù din kúù din
Adivinación lanzada para el Molde
Que se arrestó por la enfermedad
Y visto sin poder ponerse de pie
Le pidieron que realizara sacrificio
El Molde oyó hablar del sacrificio y lo realizó
Él terminó la realización del sacrificio y se puso fuerte
Él diría 'yo he ofrecido sacrificio'
'Yo he ofrecido el sacrificio de Òkànràn din din kúù din kúù din
Yo he realizado el sacrificio de Òkànràn din din kúù din kúù din
Es lo que el Molde está entonando en la tienda del herrero hasta la fecha

Òkànràn Òdí B
Ifá pé kí eléyìun ó mó dìín ebo tí ón bá yàn fún. Nnkan tí Ifá bá bèèrè gaan ni kó fún Ifá. Kò gbodò dín.

Di n din kúù din
Olòkànràn di n din kúù din
A díá fún Olòkànràn
Níjó tí n relé Ìdin lo rèé dínwó
Wón ní kó rúbo
Òkùnrùn bóo bá dínwo
A ó sì díìngùn
Òkànràn mó relé Ìdin lo rèé dínwó mó.

Òkànràn Òdí B
Ifá le pide a esta persona que no reduzca el sacrificio prescrito para él. Él debe ofrecer lo que se requiere de él exactamente.

Di n din kúù din
Olòkànràn di n din kúù din
Adivinación lanzada para Olòkànràn
En el día él iba a la casa de Ìdin para negociar los costos del sacrificio
Le pidieron que realizara sacrificio
Usted compra, si usted reduce los costos
Nosotros reduciríamos la medicina
Òkànràn, no vaya a la casa de Ìdin para altercar (disputa, regateo) de nuevo para la reducción en los costos.


Òkànràn Ìrosùn A
Ifá pé ayé ó ye eléyìun; nnkaan rè ò níí bàjé. Ifá pé Obìnrin tí eléyìun ó fèé tàbí tó ti fé le díè. Ifá pé kó móo sòrò tó dáa lénu kí wón ó baà fi Obínrin òhún jìn ín.

Òkànràn roro jèjèèjè
A díá fún Bàtá
Èyí ti n lo rèé gba Koko Obìnrin Sàngó
Bàtá ní n lòó gba Koko
Sàngó sì nìí
Èèyàn líle ni
Obínrin sì wo mó Bàtá
Ó ní dandan, òún ó fé e
Òun ó ti wáá se?
Sàngó ló sì jé ení ó le yìí
Bàtá n pé òun ò fé
Obìnrin bá kó to Bàtá lo
Bàtá bá gba Koko
Inú bá n bí Sàngó bò
Sàngó n bò wáá bá Bàtá jà
Bàtá bá nàró
Ní n pé Olúbámbí
Fi jìn mí
Olúbámbí, fi jìn mí
Fòràan Koko jìn mí
Gégé bí Sàngó tí n gbésè
Ni Bàtá n se
Ni Bàtá bá tún ké
Mo gba Koko ná
Mo gba Koko ná
Fi Koko jín mí
Sàngó níwo Bàtá
Lò n sòrò
Ní sì n bá esè òun mu
Ó ló dáa
Òun bùn o ní Koko náà
Òkànràn roro jèjèèjè
A díá fún Bàtá
Èyí ti n lo rèé gba Koko Obìnrin Sàngó
Ebo n wón ní ó se
Bàtá gbébo nbè o rúbo
Rírú ebo, èèrù àtùkèsù
E wáá bá ni ní Jèbútú aya
Jèbútú aya làá bá ni lésè Oba Òrìsà.

Òkànràn Ìrosùn A
La vida agradaría a esta persona; sus cosas no se podrían estropear. Acerca de la mujer de esta persona, (su novia o esposa), Ifá dice que ella es un enfrentamiento difícil. Ifá lo manda tener las declaraciones buenas tal que la mujer sería permanentemente su esposa.

Òkànràn roro jèjèèjè
Adivinación lanzada para Bàtá
Que iba casarse a Koko, la mujer de Sàngó,
Es Bàtá que agarro a Koko
Pero aquí esta Sàngó
Siendo una persona muy difícil
A pesar de esto, la mujer adherida enérgicamente a Bàtá
Diciendo que ella se casaría a el por todos los medios
'¿Qué yo haría ahora'? Bàtá se preguntó
'Sàngó es muy difícil y esta mujer esta pegada a mí'
Él se negó a la propuesta
Pero la mujer sin el aviso empaco en su casa
Salio sin opción, él aceptó Koko
Sàngó se puso muy enfadado y estaba viniendo con la gran furia
Sàngó estaba viniendo a luchar con Bàtá
Bàtá se ponía de pie
Diciendo 'Olúbámbí'
'Perdónela para mí'
'Olúbámbí, abandónela para mí'
'Perdóneme la causa de Koko'
Y rítmicamente, los pasos de Sàngó
Emparejaron los golpes de tambor del tamborileo de Bàtá
El tambor de Bàtá sonaba de nuevo en el tono alto
'Yo he tomado Koko
'Yo he tomado Koko
'Pero la perdona para mí'
Sàngó razonó entonces 'Usted Bàtá
Usted estaba formando su golpe de tambor
Emparejó mis pasos
Eso esta bien Sàngó dijo
Yo doy Koko permanentemente a usted
Òkànràn roro jèjèèjè
Adivinación de lanzada para Bàtá
Ése iba tomar a Koko, la mujer de Sàngó,
El sacrificio era el antídoto que se prescribió para él
Bàtá oyó hablar del sacrificio y lo realizó
Ofreciendo de sacrificio y regalos libres a Èsù
Venga y encuéntresenos rodeado por las esposas
Uno se encuentra rodeado por las esposas a los pies del rey de todos los Òrìsàs.

Òkànràn Ìrosùn B
Ifá pòun pé ire fún eléyìun lódò oba, lódò ìjòyè, àti lódò àwon èèyàn nlá. Yóó nípon láyé, yóó sì rí ìfà je.

Máílo Awo Ode ló díá fún Ode
Ode ní n re Igbó méje èlùjù méje
Àgbébìkan jìfà, Awo Olóyè
Ló díá fún Olóyè
Wón ní kó rúbo kó lè baà róyèe baba è je
Ode ní n bèèrè lówó Ifá
Ayé ye òun báyìí?
Wón ní kí Ode ó rúbo
Wón ní Isu lebo è
Odé bá kó Isu wá
Wón bá kó ìdajì fún Ode
Àwon Babaláwo je ìdajì yókù lérù
Odé bá rúbo
Wón ní odún odúnnìí ni olàa rè dé
Odé bá korí sí aginjù
Ó bá fisu sórí iná
Ó gorí égún lo
Iná isu bá n rú túú
Àwon ká sì ti rìn rìì rìn
Tí ón ti sonù sínú ìgbé láti ìgbà ìwásè
Ni ón bá rí èéfín iná
Àwon ò sì ti rí oúnje je fún ijó mèta
Wón bá to òye iná lo
Wón dé ibè
Wón bá Ode tó fisuú ná
Ni ón bá jókòó ni ón jeun
Wón ní ìwo Ode làwón n bá lo ilé
Odé lóun ò tó irúu wón gbà sódò
Ó bá kó won to Oba lo
Obá ní ó móo kó won lo ilé è
Àwon Àgbébìkan jìfà Awo Olóyè
Tó dífá fún Olóyè
Àwon náà ti rúbo
Ngbà ó di odún
Bí ón tí n kò erù isu méwàá fún Ode
Ni Ode n kó márùún lòó fún Oba
Odún Olà Odé bá pé
Ifá pé eléyìun ó rífà je
Máílo Awo Ode ló díá fún Ode
Ode ní n re Igbó méje èlùjù méje
Wón ní kí Ode ó rúbo sílè kó tóó lo
Odé gbébo nbè ó rúbo
Àgbébìkan jìfà, Awo Olóyè
Ló díá fún Olóyè
Wón ní kó rúbo lódúnnìí kó lè baà rífà je láíláí
Òun náà gbébo nbè ó rúbo
Odé rúbo: Olóyè náà rúbo
Kín ní n wá waá bò wá gerere?
Ifá
Ifá ní n wá waá bò wá gerere
Ifá


Òkànràn Ìrosùn B
Ifá desea bien a esta persona. Ifá dice que él recibiría bien la recepción de los reyes, jefes y personalidades. Ifá asegura que él conseguiría los regalos gratuitamente.

Máílo el Babaláwo del Cazador lanza la adivinación para el Cazador
El Cazador iba a los siete renombrados bosques y arbustos,
Àgbébìkan-jìfà el Babaláwo del Jefe superior
La adivinación lanzada para el Jefe superior
Le pidieron que realizara sacrificio para ascender al trono de sus antepasados
El Cazador fue uno que pregunto a Ifá,
Si la vida lo agradaría o no
Ellos le pidieron al Cazador que realizara sacrificio
Ellos le dijeron que sus artículos de sacrificio eran principalmente tubérculos de ñame
El Cazador trajo los tubérculos de ñame
Ellos dieron la mitad de los ñames totales que él trajo
El Babaláwo tomó la mitad para ellos como su regalo libre
El Cazador realizó el sacrificio
Ellos le dijeron que sus riquezas vendrían a él el mismo año
El Cazador salio entonces para el Bosque
Él puso algunos tubérculos de ñame en el fuego para asar
Él ascendió a su campamento oculto
Los humos del fuego subieron entonces al cielo
Entretanto, algún grupo de personas había viajado y viajado
Ellos habían perdido su camino durante un tiempo muy largo
Ellos vieron el humo de una distancia lejana
Y no habían tenido comida durante tres días
Ellos empezaron rastreando la fuente del humo
Ellos llegaron al sitio
Y se encontraron con el Cazador con Ñames que asan en el fuego
Ellos se sentaban y hacían alguna comida para comer
'Usted es uno, nosotros somos seguidores de casa ', ellos dijeron
Pasmado, el Cazador dijo, 'yo no soy digno de ser seguido a casa'
Él los llevo al rey
El Rey pidió entonces que él los llevara a casa
Entretanto los sacerdotes 'Àgbébìkan-jìfa' el sacerdote del jefe superior
Que lanzo adivinación para el jefe superior
Ellos habían ofrecido su sacrificio también
Cuando era un ciclo del año
El visitante empezó dando diez cargas de tubérculos de ñame a su organizador, el Cazador
El Cazador daría cinco al rey
El año de riquezas del Cazador se volvió una realidad
Ifá dice que esta persona conseguiría los regalos gratuitamente para disfrutarlos
Máílo el Babaláwo del Cazador lanza la adivinación para el Cazador
El Cazador iba a los siete renombrados bosques y arbustos,
Ellos le pidieron al Cazador que ofreciera el sacrificio antes de salir
El Cazador oyó hablar del sacrificio y lo realizó
Àgbébìkan jìfa el Babaláwo del Jefe superior
Adivinación lanzada para el Jefe superior
Le pidieron que realizara sacrificio este año actual para conseguir los regalos gratuitamente hasta la eternidad
Él también además oyó hablar del sacrificio y lo realizó
El Cazador realizó su sacrificio; así hace al jefe
¿Qué está viniendo a buscarnos en multitud?
Los regalos libres
Los regalos libres están viniendo a buscarnos en multitud
Los regalos libres.

Òkànràn Òwónrín A
Ifá loun pé ire fún ení ó dá Odù yìí. Ayé ó ye é; gobgbo nnkan tó ti se see se tí ò lójú. Ifá pé gbogbo è ní ó lòójú Ebo ni kó rú. Ifá pé àwon Olórun ó ta eléyìun lóre.

Òkànràn Òwónrín onílè ló làre
Àjòjì won ò mesèe lè
Àjòjì Ì bá mesè ilè won a bàlú jé
A díá fún Awógbádé
Omo Olórun figbá bòwà molè
Ebo n wón ní ó se
Awógbádé ló se gogbo nnkan ni ò lójú
Wón ní gbogbo è ní ó lojú
Awógbádé bá rúbo
Ayé bá ye é
Ní wá n jó n ní n yò
Ní n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòón wí
Òkànràn Òwónrín onílè ló làre
Àjòjì won ò mesèe lè
Àjòjì I bá mesè ilè won a bàlú jé
A díá fún Awógbádé
Omo Olórun figbá bòwà molè
Olórun tó figbá bòwà mólè
Odún Odún yìí ní ó si
Olórun tó figbá bòwà mólè

Òkànràn Òwónrín A
Ifá desea bien a esta persona. La vida lo agradaría. Él había intentado y probado sus manos en algunas cosas sin hacer progreso. Ifá dice que todo tendría éxito pero él debe realizar sacrificio. Ifá dice que algunas personas celestiales le golpearían regalos.

Òkànràn Òwónrín, los dueños de la tierra se vindican
Los visitantes no conocen la historia, ellos habrían desacreditado la ciudad
Adivinación lanzada para Awógbádé
El niño de Dios que cubrió el carácter con la calabaza
Le pidieron que realizara sacrificio
Awógbádé estaba probando su mano en las cosas sin tener éxito
Ellos lo aseguraron que todo estaría bien
Awógbádé realizó el sacrificio
La vida lo agradó
Él estaba bailando entonces y estaba regocijando
Él estaba alabando sus Babaláwos
Sus Babaláwo estaban alabando Ifá
Él dijo que era exactamente como sus Babaláwos habían dicho
Òkànràn Òwónrín, los dueños de la tierra se vindican
Los visitantes no saben la historia de la tierra
Si los visitantes hubieran sabido la historia, ellos habrían desacreditado la ciudad
Adivinación lanzada para Awógbádé
El niño de Dios que cubrió el carácter con la calabaza
El dios que cubrió el carácter con la calabaza
Él lo abriría este año actual
Dios cubrió el carácter con la calabaza

Òkànràn Òwónrín B
Ifá péléyìun ò gbodò sánnáání sí Obìnrin è. Ire kán n yo bò wá. Kó mó fi ire náà se fàárí kó mó baà tàràkà lójó iwájú. Ire tó bá kó yojú sí i ni kó gbá mú; Ire pò fún eléyìun sùgbón tó bá so ti àkókó nù, kò dára o.

Okàn wóòn wóòn
Awo Ajá ló díá fún Ajá
Ajá níí soko Àlá Òru
Wón ní ó rúbo
Àlá Òru nìyàwó Ajá
Ajá bá n sánnáání Àlá Òru
Òun náà ni Ajá n se báyìí sí?
Àlá Òru bá kòyìn sí Ajá
Ajá bá pe Àlá Òru; pe Àlá Òru
Àlá Òru ò bá dáhùn mó
E é ri bó bá di lálé
Ajá ó móo hu
Àlá òrun ní n wá kiri
‘Wón ní àwon ò wí fún o’
‘Lójó kìíní pé ó mó fi ire è re se fáàrí’
Okàn wóòn wóòn
Awo Ajá ló díá fún Ajá
Ajá níí soko Àlá Òru
Wón ní ó sá káalè ebo aya ní ó se
Ajá ìwo loò seun
Ìwo loò sèèyàn
Ìgbà tóò sebo
Ìgba tóò tù èèrù
Ìwo wo Ifá ojóhun bí tí n se

Òkànràn Òwónrín B
Ifá le pide a esta persona que no sea ningún insensible a su esposa. Una cierta fortuna está viniendo a él. Él no debe jugar con la fortuna tal que no crearía un cuello de botella para él. La primera fortuna buena que viene a él debe agarrarse, como allí tantas fortunas buenas que vienen a su camino; pero si él debe extrañar el primero, podría crear un problema en el futuro.

Okàn wóón wóón
El Babaláwo del Perro lanza adivinación para el Perro
El Perro era el marido de Àlá Òru
Le pidieron que ofreciera sacrificio
Àlá Òru es la esposa del Perro
El perro la descuidó y la trató andrajosamente
'Es mí Perro está comportándose a esta manera', ella se preguntó
Ella desechó el Perro después
Después el Perro devolvió casa y llamó a su esposa
Él no recibió ninguna contestación de Àlá Òru
Usted lega todo el aviso que una vez es sombrío
El Perro aullaría
Él realmente está echando una mirada alrededor para Àlá Òru
¿Nosotros no le dijimos, ellos lo recordaron?
Que usted no debe jugar con sus cosas buenas
Okàn wóón wóón
El Babaláwo del Perro lanza la adivinación para el Perro
El Perro era el marido de Àlá Òru
Le pidieron cuidar de la tierra y realizar sacrificio significativo para las esposas
Usted el Perro, 'usted no es bastante amable'
Usted no es humano
Como usted no realizó ningún sacrificio prescrito
Ni dio los regalos libres
Vea la adivinación del otro día que demuestra verdad

Òkànràn Òbàrà A
Ifá pé ire ó tòó eléyìun lówó, Obìnrin rere ni eléyìun ní yóó sí bímo fún un lópòlopò.

Okàn bàbààbà Awo ilé Olóbà
A díá fún Olóbà Abèdú
Omo a yín gínní gínní bomo lénu
Wón ní ó rúbo
Olóbà Abèdú ní n bèèrè lówó Ifá
Pé òún rífà je bí?
Ayé òún dára báyìí?
Wón ní ayée rè ó dáa
Wón ní yóó bìí omo lópòlopò
Enú àwon omo è ó sì tómú
Nnkan è ò sì níí bàjé
Olóbà Abèdú bá rúbo
Omo ó nì mòmó mó
Ní bá n yín gínní gínní sómo lénu
Ní wá n jó n ní n yò
Ní n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Òkàn bàbààbà Awo Ilé Olóbà
A díá fún Olóbà Abèdú
Omo a yín gínní gínní bomo lénu
Wón ní ó sá káalè ó jàre ebo ní ó se
Olóbà Abèdú gbébo nbè ó rúbo
Kín lOlóbà n je?
Ifá
Ifá lOlóbà n je
Ifá

Òkànràn Òbàrà A
Ifá desea bien a esta persona. Las cosas buenas vendrían a él. Él tendría una esposa buena y la mujer le daría muchos niños.

Òkàn bàbààbà, el Babaláwo de la casa de Olóbà,
Adivinación lanzada para Olóbà Abèdú
El niño de 'a yín gínní gínní bomo lénu'
Le pidieron que realizara sacrificio
Olóbà Abèdú estaba preguntándole a Ifá
'¿Cómo yo podría conseguir regalos gratuitamente?
'¿Mi vida estaría bien?'
Ellos dijeron que su vida estaría bien
Y que él tendría muchos niños
Sus niños tendrían el éxito en la vida
Sus cosas no se pondrían estropear
Olóbà Abèdú realizó el sacrificio
Los niños llegaron a ser tantos
Él empezó a cortar pedazos de comida en la boca de los bebés entonces
Él empezó a bailar y regocijar entonces
Él estaba alabando sus Babaláwos
Sus Babaláwos estaba alabando Ifá
Él dijo que era exactamente como sus Babaláwo habían dicho
Òkàn bàbààbà, el Babaláwo de la casa de Olóbà,
Adivinación lanzada para Olóbà Abèdú
El niño de 'a yín gínní gínní bomo lénu'
Le pidieron que cuidara de la tierra y realizara el sacrificio
Olóbà Abèdú oyó hablar del sacrificio y lo realizó
¿Qué Olóbà está disfrutando?
Regalos libres
Regalos libres son lo que Olóbà está disfrutando
Regalos libres

Òkànràn Òbàrà B
Ifá pé nnkan ìdílé àwon eléyìun kán n be nlè. Ifá pé kó mó jèé kí nnkan òhún ó parun. Ifá pé nípa nnkan tí eléyìun n bèèrè, nnkan ìdílé won kán n be tí ón ti patì, kó lòó wádìí nnkan òhún kó mó jèé pé nnkan ìdílé yìí ní ó móo dà á láàmú nínú nnkan tó bèèrè fún.

Agogo sékété Awo ilé Olóbà
Ló díá fún Olóbà ni kùtùkùtù Òwúrò
Wón ní ó rúbo kí nnkan ogúun babaa wón ó mó leè parun
Nnkan ogúun baba àwon ò parun báyìí?
Wón ní ó rúbo
Wón ní béèyàn bá gbó tó tó
Òdò àwon baba è náà ní ó lo
Baba tí n pè ní baba àtijó náà ní ó tò lo
Láì lo sí ìkangun won mó
Wón ó da padà ni
Wón ní kó rúbo
Kó lòó se ojúse àwon baba won láti ilè
Eégún, ilé Olóbà ni
Òòsà, ilé Olóbà ni
Gbogbo ará orún pátá, ilé Olóbà ni
Wón ní kí Olóbà ó mó jèé ó run
Ni ón bá rúbo
Ni gbogbo nnkan wón gún
Ayé ye wón
Ní wá n jó n ní n yò
Ní n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ni béè làwon Babaláwo tóùn wí
Agogo sékété Awo ilé Olóbà
Ló díá fún Olóbà ni kùtùkùtù Òwúrò
Ebo n wón ní ó se
Wón ní kí wón ó rúbo kógúun baba won mó baà parun
Wón gbébo nbè wón mó rúbo
E mó mò jé ó run
Egúngún ilé Olóbà
E mó mò jé ó run
Òrìsà ilé Olóba
E mó mò jé ó run
Gbogbo nnkan tí n be nílé Olóbà
E mó mò jé ó run.

Òkànràn Òbàrà B
Hay un objeto de herencia ancestral en la casa de esta persona. Ifá lo manda no permitir la cultura (cultivo) para morirse. Tocante a que esta persona está pareciendo (mirando), es estos mismos valores ancestrales que han sido abandonados que él debe ir e investigar tal que no lo preocuparía de nuevo en el futuro.

Agogo sékété, el sacerdote de la casa de Olóbà,
Adivinación lanzada para Olóbà al principio
Le pidieron que realizara sacrificio tal que su monumento ancestral no se moriría
¿Cómo este monumento no se moriría?
Le pidieron que realizara el sacrificio
Ellos le dijeron que cuando uno se pone viejo y anciano
Él ascendería para encontrarse a sus antepasados
Es a los mismos padres que eran al principio conocido ese uno volvería
Sin ir a su ambiente familiar
Le enviarían de regreso
Le pidieron que realizara el sacrificio
Él debe observar la práctica de sus padres que conocidos desde la creación entonces
Las mascaradas pertenecen a la casa de Olóbà
Todas las Deidades pertenecen a la casa de Olóbà
Todos los progenitores son los venerados en la casa de Olóbà
Ellos le aconsejaron que no permitiera la práctica para morirse
Ellos realizaron el sacrificio
Sus cosas se pusieron exitosas
La vida los agrada así
Él estaba bailando entonces y estaba regocijando
Él estaba alabando su Babaláwo
Su Babaláwo estaba alabando Ifá
Él dijo que era exactamente como su Babaláwo había dicho
Agogo sékété, el sacerdote de la casa de Olóbà,
Adivinación lanzada para Olóbà al principio
Él fue advertido para realizar el sacrificio
Le pidieron que realizara el sacrificio tal que su monumento ancestral no se moriría
Ellos todos oyeron hablar del sacrificio y lo realizan
Por favor no le permita morirse
La mascarada en la casa de Olóbà
Por favor no le permita morirse
Las Deidades de la casa de Olóbà
Por favor no le permita morirse
Todo de importancia hereditaria en la casa de Olóbà
Por favor no le permita morirse

Òkànràn Ògúndá A
Ifà pé oún pé ire fún eléyìn. Yóó gbòó, yóó tòó. Ire rè ò níí jùnù sùgbón kó rúbo e dada.

Òkànràn Rangún Rangún
Òkànràn kangè kangè
Bó lè kaángún kó kaángún
Bó lè kangè kó kangè
Òrò tó bá kán Ogún
A móo kan Àádóta
A díá fún Òrúnmìlà
Níjó ti n lo rèé fi Mórinéwà omo Arèsà sobìnrin
Òrúnmìlà ló fé Mórinéwá omo Arèsà
Àwon méjèèjì n bá ayéé lo
Ngbà ó di ojó kan
Mórinéwà aya Òrúnmìlà bá ní òún n lo
Ó lóun ò fé Òrúnmìlà mó
Àwon ebíi Mórinéwà sì ti mo Òrúnmìlà
Tí ón ti jo gbé gbéé gbé
Ngbà Òrúnmìlà so soo so
Ti ò gbó
Òrúnmìlà bá ní kó móo lo
Bó ti pèyìn dà tán
Òrúnmìlà bá sòrò ìwúrí fún un
Ó lÓkànràn kangún kangún
Òkànràn kangè kangè
Bó lè kaángún kó kaángún
Bó lè kangè kó kangè
Òrò tó bá kán Ogún
A móo kan Àádóta
A díá fún Òrúnmìlà
Yóó fi Mórinéwà omo Arèsà sobìnrin
Mórinéwà wáá bùse gàgà
Ó lóun ò fé Ifá mó
Ó lóun n lo
Ifá ní bí bá n lo
Ó ní kó kí Eésà lÓmù
Ó ní bó bá wolé tán
Kó kí Ejemu lÓrópo
Kó kí Àgbìgbò kan Àgbìgbò kàn
Ti wón n jeyìn ní Ìjèkí ilé
Ti wón fí n kí wón ní aráà ladè gún
Omo a rójú epo pónbe
Omo asènì epo gùdù gùdù lalò
Mórinéwà ko hàáà
Àwon Baba òun náà lo ti kì tán yìí
Ifá pé ire eléyiun ò níí dànù
Mórinéwà bá padà sódò Òrúnmìlà.


Òkànràn Ògúndá A
Ifá desea bien a esta persona. Él Mundo vive para ponerse viejo y anciano. Sus cosas buenas no lo eludirían, pero él debe realizar sacrificio.

Òkànràn kangún kangún
Òkànràn kangè kangè
Si involucra mascaradas, permítale ser
Si involucra el pecho, permítale ser
Discusiones sobre los veintes
Pueda involucrar cincuentas
Adivinación lanzada para Òrúnmìlà
En el día él iba a tomar Mórinéwà. La hija de Arèsà como esposa
Òrúnmìlà se casaron con Mórinéà la hija de Arèsà
Los dos estaban disfrutando la vida
En un día fatal
Mórinéwà resolvió para divorciarse de Òrúnmìlà
Ella dijo que ella no quiere a Òrúnmìlà de nuevo como su marido
Entretanto la familia de Mórinéwà había sabido
Òrúnmìlà durante un tiempo muy largo
Ellos se habían relacionado y habían vivido entre sí previamente con armonía
Después de que Òrúnmìlà la habían apaciguado continuamente
Ella se negó a pandearse
Òrúnmìlà le pidieron que fuera
Inmediatamente ella retrocedió
Òrúnmìlà dijeron algunas palabras de oración
Él dijo Òkànràn kangún kangún
Òkànràn kangè kangè
Si involucra mascaradas, permítale ser
Si involucra el pecho, permítale ser
Discusiones sobre los veintes
Pueda involucrar cincuentas
Adivinación lanzada para Òrúnmìlà
En el día él iba tomar a Mórinéwà, la hija de Arèsà como esposa,
Mórinéwá pensó ahora después
Ella dijo que ella quiso discontinuar el matrimonio
Ella dijo que ella quiso un divorcio
Ifá le dijo que cuando ella estaba saliendo
Ella debe saludar al Jefe Onísà en la ciudad de Òmù
En entrar en su casa
Ella debe saludar al Jefe Ejemu en la ciudad de Orópo
Ella debe saludar a la renombrada familia de Àgbìgbò
Eso come aceite de palma de aceite de semilla en la ciudad de Ìjèkí
Eso hace a las personas referirse a ellos como Aráà ladè gún
El niño de UN rójú epo pónbe
El dador de aceite de palma libre en cantidades pesadas en jornada de regreso
Sorprendida, Mórinéwà exclamó
Usted ha cantado todos los seudónimos de mis padres
Ifá dice la fortuna buena de esta persona no lo eludiría
Mórinéwà regresó como resultado a la casa de Òrúnmìlà.


Òkànràn Ògúndá B
Ifá pé àlejò kán n bò wáá bá eleyìun. Àjòjì ni. Kí eléyìun ó gba àlejò náà; kó sì gbà á sílé.

Awo níí yalé Awo
Ìsègùn níí yalé àwon Ìsègùn
Àáèrí n ló ya Òyó Àjàká
N ló gba tilé Ògidì
N ló yalé ló ké sí Abe
Awo ò níí yalé Awo kÁwo ó jéfó
A díá fún Olòkànràn
Níjó ti n lo rèé yalé Ògúndá
Wón ní ó rúbo
Ògúndá ni nnkan rè ò se dáadáa
Olòkànràn bá dé ibe
Ló bá se Ifá fún Ògúndá
Ni gbogbo nnkan Ògúndá tó ti bàjé
Ní bá n dára
Wón sì ti so fún Ògúndá pé àlejò kán n bò
Wón ní bó bá ti dé ni kó gbà á
Òun ó sì mò títí tó fi se Olòkànràn lálejò
Iré bá kún òdèdè Ògúndá
Okàn è balè
Ó ní ìsinmi
Omo weere kún Òdèdè Ògúndá
Ijó ní n jó ayò ní n yò
Àwon Babaláwo ní n yìn
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Awo níí yalé Awo
Ìsègùn níí yale àwon Ìsègùn
Àáperí n ló ya Òyó Àjàká
N ló gba tilé Ògidì
N ló yalé ló ké sí Abe
Awoò níí yalé Awo kÁwo ó jèfó
Aída fún Olòkànràn
Níjó ti n lo rèé yalé Ògúndá
Ìgbà tÒlòkànràn yalé Ògúndá
Omo wèrè were lódèdè Awo ò
Omo were.


Òkànràn Ògúndá B
Ifá dice que el visitante está viniendo a su persona. El visitante es un extraño. Esta persona debe alojarlo.

Un Babaláwo debe consultar un Babaláwo compatriota
Un curandero va a un curandero
Los Àápori del rey fueron a la ciudad de Òyó Àjàká
Llegando al Ògidi de la casa
Y en la casa llamada en Abe
Un Babaláwo nunca entraría en la casa de un compatriota y comería verdura tiesa
Adivinación lanzada para Olòkànràn
En el día él estaba echando ramas en la casa de Ògúndá
Ellos le dijeron que ofreciera sacrificio
Ògúndá estaba teniendo un tiempo difícil
Olòkànràn llegó allí
Y preparó una porción de Ifá para Ògúndá
Todo lo que antes había estado desesperanzado para Ògúndá
Se puesto mejor
Entretanto, se habían advertido Ògúndá sobre un visitante inminente
Le dijeron que lo alojara en su llegada
Ògúndá ni siquiera no recordaron hasta que él hubiera entretenido a Olòkànràn
Todas las cosas buenas completas de la casa de Ògúndá
Él tenía descanso de mente
Y paz
Los niños pequeños llenaron su casa
Él estaba bailando y estaba regocijando
Él estaba alabando su Babaláwos
Sus Babaláwos estaban alabando Ifá
Él dijo que era exactamente como su Babaláwos había dicho
Un Babaláwo debe consultar un Babaláwo compatriota
Un curandero va a un curandero
Los Àáperi del rey fueron a la ciudad de Òyó Àjàká
Llegando a la casa Ògidì
Y en la casa llamada en Abe
Un Babaláwo nunca entraría a otra casa de Babaláwo y come verdura dura sin carne
Adivinación lanzada para Olòkànràn
En el día él estaba echando ramas en la casa de Ògúndá
Cuando Òkànràn entra en la casa de Ògúndá
Venga y vea a muchos niños pequeños en la casa del Babaláwo
Niños pequeños.

Òkànràn Òsá A
Ifá pé ire ò níí bó jùnù lówó eléyìun; Sùgbón kó rúbo dáadáa. Kí nnkan ó mó bàjé ni kó rúbo sí. Ifá pé nnkan ò níí bàjé. Bí bá n lo òkèèrè, gégé ire ní ó se; yóó gbàá ire mú níbè.

Òkànràn sáà sáà
Awo Àsá ló díá fún Àsá
Àsá ní n lo sí oko ìwáje
Oko ìwáje tóun n lo yìí
Òun rí se nbè?
Wón ní kí Àsá ó rúbo
Wón ní kò níí sánwó re ilé
Ire ó to lówó
Àsá bá rúbo
Ó rúbo tán, ayé bá ye é
Ni nnkan è dáa
Ire ò tàsé è
Òun náà ò tàsé ire
Gbogbo nnkan ní n gún régé
Ijó ní n jó ayò ní n yò
Àwon Aláwo ní n tìn
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Òkànràn sáà sáà
Awo Àsá ló díá fún Àsá
Àsá ní n lo sí oko ìwáje
Wón ní ó sá káalè ebo ni kó rú kó tó móo lo
Àsá sì gbébo nbè ó rúbo
Òkò Àsá ì í balè ó sánwó
Àwódì ó níí balè kó pòfo
Ire gbogbo ò
Mó tàsé Awo
Ire gbogbo

Òkànràn Òsá A
Ifá dice que las cosas buenas no eludirían a esta persona. Él debe realizar sacrificio bien. Él está preguntando si sus cosas no se podrían estropear. No se estropearian. Si él viaja, él se encontraría con su fortuna buena en su destino.

Òkànràn sáà sáà
El Babaláwo del Halcón lanzó adivinación para el Halcón
El Halcón iba a defenderse
'Esta evasión defendiéndose por que yo voy'
'Me ganaría'? Él preguntó
Ellos le dijeron que realizara sacrificio
Ellos le dijeron que él nunca iría con manos vacías
Y que cosas buenas llegarían a él
El Halcón realizó sacrificio
Él terminó la ejecución del sacrificio y la vida lo agradó
Sus cosas se pusieron buenas
Sus cosas buenas no lo eludieron
Él tampoco extrañó sus cosas buenas
Todo resultó ser un éxito
Él estaba bailando y estaba regocijando
Es el Babaláwo que él estaba alabando
El Babaláwo estaba alabando Ifá
Él dijo que era exactamente como su Babaláwo había dicho
Òkànràn sáà sáà
El Babaláwo del Halcón lanzó adivinación para el Halcón
El Halcón iba a defenderse
Le pidieron cuidar de la tierra y realizar el sacrificio
La cabeza del Halcón sobre el sacrificio y lo realizó
El picada de un Halcón nunca tocaría la tierra y perdería
El Cometa nunca tocaría la tierra y regresaría con manos vacías
Todas las cosas buenas
No eluda al Babaláwo
Todas las cosas buenas

Òkànràn Òsá B
Ifá pé eléyìun ò níí kú ní kékeré.

Òkànràn sálè kóo sákùúta
Awo Okó ló díá fún Okó
Okó níí somo Onírèe Sànbe
Wón ní kí Okó ó rúbo
Wón ní yóó móo gbó ni
Enìkan ò níí gbó ikú è
Òkànràn sálè kóo sákùúta
Awo Aso ló díá fún Aso
Aso níí somo Onírèe Sànbe
Wón ní kí Aso ó rúbo
Wón ní yóó móo gbó ni
Eníkan ò níí gbó ikú è
Òkànràn sálè kóo sákùúta
Awo Ilé ló díá fún Ilé
Ilé níí somo Onírèe Sànbe
Wón ní kí Ilé ó rúbo
Ilé náà rúbo
Wón ní won ò níí gbó ikúu won
Ayé ye wón
Won ò kú
Emíi wón gùn
Ó dáa fún on
Ní wón wá n jó ní wón n yò
Wón n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Òkànràn sálè kóo sákùúta
Awo Okó ló díá fún Okó
Wón ní ó sá káslè ebo ní ó se
Okó gbébo nbè ó rúbo
Òkànràn sálè kóo sákùúta
Awo Aso ló díá fún Aso
Wón ní ó sá káalè ebo ní ó se
Aso gbébo nbè ó rúbo
Òkànràn sálè kóo sákùúta
Awo Ilé ló díá fún Ilé
Wón ní ó rúbo sáìkú araa re
Ilé gbébo nbè ó rúbo
Eboo wón wáá dà
Wón lá ì í gbókú okó
A ì í gbó ikú Aso
A ì í sìí gbó ikú Ilé
À se bó gbó.

Òkànràn Òsá B
Esta persona viviría para ponerse vieja.

Òkànràn, golpea la tierra y golpea piedras
El sacerdote del Azadon lanzó adivinación para el Azadon
El Azadón es un niño de Onírèe Sànbe
Le pidieron que realizara sacrificio
Ellos le dijeron que él se pondría viejo
Nadie oiría hablar de su muerte
Òkànràn, golpea la tierra y golpea piedras
El sacerdote de la Tela lanzó la adivinación para la Tela
La Tela es un niño de Onírèe Sànbe
Le pidieron que realizara sacrificio
Ellos le dijeron que él se pondría viejo
Nadie oiría hablar de su muerte
Òkànràn, golpea la tierra y golpea piedras
El sacerdote de la Madre Tierra lanzó adivinación para la Madre Tierra
La Madre Tierra es un niño de Onírèe Sànbe
Le pidieron que realizara sacrificio
La Madre Tierra realizada sacrificio como hacen otros
Ellos no dijeron a nadie oír hablar de su muerte
La vida agradó a todos
Ellos no se murieron
Ellos tenían vida larga
Estaba bien para ellos
Ellos empezaron a bailar y regocijar entonces
Ellos estaban alabando su Babaláwo
Su Babaláwo estaba alabando Ifá
Ellos dijeron que era como su Babaláwo había dicho
Òkànràn, golpea la tierra y golpea piedras
El sacerdote de Azadón lanzó adivinación para el Azadón
Le pidieron cuidar de la tierra y realizar sacrificio
El Azadón oyó hablar del sacrificio y lo realizó
Òkànràn, golpea la tierra y golpea piedras
El sacerdote de la Tela lanzó la adivinación para la Tela
Le pidieron cuidar de la tierra y realizar sacrificio
La Tela oyó hablar del sacrificio y lo realizó
Òkànràn, golpea la tierra y golpea piedras
El sacerdote de la Madre Tierra lanzó la adivinación para la Madre Tierra
La Madre Tierra fue pedida realizar sacrificio para fortificarlo contra la muerte
Sus sacrificios demostraron eficacia
Ellos dijeron que nadie oiría hablar del fallecimiento de un Azadón
Nadie oiría la extinción de la Tela
Nadie oiría la muerte de la Madre Tierra
Sólo que se ha puesto viejo


Òkànràn Ìká A
Ifá pè yóó ye eléyìun. Nnkan è ò níí bàjé, Sùgbón kó rúbo.

Òkànràn kárò kárò
Babaláwo Kannakánná
Ló díá fún Kannakánná níjó tí n fomi ojú sògbérè omo
Òún le bímo báyìí?
Wón ní ó rúbo
Wón ní Òja méjì lebo è
Yóó fi òjá méjì kún ebo rú
Ó sì gbébo nbè ó rúbo
Eyé mòmò róso
Ó mòmò gbàjá ò
Eyé wé gèlè funfun gbòò
Ayé ye é tán
Ló bá bóójó
Ní n seyé wé gèlè funfun gbòò
Eyé wé gèlè funfun gbòò
Eyé mòmò róso ó gbàjá ò
Eyé wé gèlè funfun gbòò

Òkànràn Ìká A
Ifá dice que estaría bien con esta persona. Sus cosas no se podrían estropear. Pero él debe ofrecer sacrificio.

Òkànràn kárò
El Babaláwo del Halcón
Adivinación lanzada para el Halcón en el día ella estaba llorando debido a niños
'¿Yo tendría niños '?
Ellos le dijeron que ofreciera sacrificio
Dos correas son su sacrificio ', ellos dijeron
Le pidieron que agregara estas dos correas al resto de Los artículos sacrificatorios
Ella oyó hablar del sacrificio y lo realizó
El pájaro había envuelto alrededor de ella una tela
Y había tomado un cinturón de cintura
El pájaro ató un puro echarpe (faja, chalina) blanco
La vida la agradó así después
Ella estaba bailando
Ella estaba cantando 'El pájaro ató un puro echarpe blanco '
Ella ató un puro echarpe blanco
El pájaro envolvió alrededor una tela y había tomado una correa
El pájaro ató un puro echarpe blanco

Òkànràn Ìká B
Ifá gba eléyìun nímònràn kó mó se nnkan tí ipáa rè ò ká. Ifá pé kó rúbo kó le móo se ìse olá. Eléyìun ó nìíyì kárí ayé.

Báà bá tó Olóláá se
A ì í se ìse Olólá
Báà bá tó Olùmòó se
A ì í se ìse Olùmò
A díá fún Kannakánná tíí sàrèmo Olúdànhìn
Wón ní ó rúbo nnkan olà
Kannakáná bá rúbo
Ni nnkaan rè bá dáa
Ó lólá
Ó lè se bírà
Ó sì le pàse
Báà bá tó Olóláá se
A ì í se ìse Olólá
Báà bá tó Olùmòó se
A ì í se ìse Olùmò
A díá fún Kannakánná tíí sàrèmo Olúdànhìn
Wón ní ó sá káalè ebo ní ó se
Kannakánná mòmò gbébo nbè
Ó rúbo
Ó wáá rúbo nígbàyí ò
Ó deni Iyì kálé ayé

Òkànràn Ìká B
Esta persona se manda para no comprometer en eso que él/ella no es capaz de lograr. Él debe ofrecer sacrificio para poder actuar como un hombre rico. Él sería popular a lo largo del mundo entero.

En uno no mide a llamarse influyente
Uno no debe comportarse como una personalidad influyente
Si uno no es académicamente competente
Uno no debe comportarse como sabio
Adivinación lanzada para el Halcón, el mayor hijo de Olúfànhìn
Le pidieron que ofreciera sacrificio para los pasos acelerados de riqueza
El Halcón realizó sacrificio
Sus cosas se pusieron buenas
Él tenía la riqueza
Él era capaz de lograr los hechos
Él se volvió una persona en una posición de responsabilidad
Si uno no mide a llamarse influyente
Uno no debe comportarse como una personalidad influyente
Si uno no es académicamente competente
Uno no debe comportarse como sabio
Adivinación lanzada para el Halcón, el mayor hijo de Olúdànhìn
Le pidieron cuidar de la tierra y realizar el sacrificio
El Halcón oyó hablar del sacrificio
Y lo realizó
Después de observar el sacrificio
Él se volvió una personalidad honorable a lo largo del mundo




Òkànràn Òtúrúpòn A
Ifá pé kí eléyìun ó rúbo. Bó bá pé òun ó lo ibì; kó móo yè é wò dáadáa kó tó móo lo. Bí Ifá bá pé kó móo lo ni kó lo.

Opón bémbé Awo ilé Alárá
Àyìnbò, Awo Osù
Ló díá fún Osù
Àwon ni ón dáfá fún èìnlójo Ìmòle
Níjó tí wón n relé Òlódùmarè
Níbi tí wón n pè ní Mékà
Èìnlójo Ìmòle ní n lo ilé Òlódùmarè
Bí ón bá lo
Nígbà tí wón ó mèe bò
Won ò níí ju mérin méta lo
Àyà bá n já won bí ón bá féé relé Òlódùmarè
Wón bá to Òrúnmìlà lo
Ilé Òlódùmarè táwon n lo yìí
Àwon se le móo pé dé padà?
Òrúnmìlà ní e jé Mékà ó móo pè yín ni
Ó ní eni tí inú è bá mó tí ó bàá lo
Ejé ó móo pè yín ni
Ó ni sùgbón e yídì síhìín
Ni ón fi dá Yídì sílè
Òrúnmìlà bá ní kí wón ó ra àgbò wá
Kí wón ó wá ewé odán wá
Kí wón ó wá dì síhìín
Ni ón bá n e ibè ní yídì
Ó ní e móo kírun tiyín nbè
Ó ní e móo mo eni tí ilé Òlódùmarè bá pè nbè
Ni ón bá n se béè
Ni ón bá n léé sí
Ní wón wá n jó ní wón n yò
Wón n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Opón bémbé Awo ilé Alárá
Àyìnbò, Awo Osù ló díá fún Osú
A díá fún èìnlójo Ìmòle
Níjó tí wón n relé Òlódùmarè
Wón tí n lo síbè won ò pé dé
Ifá ní wón ó móo gbélé kí tiwon
Ilé mòmò yá o
Ilé yìí wúlò
Ni gbogbo ayé n pè ní Iléyá

Òkànràn Òtúrúpòn A
Ifá le pide a esta persona que ofrezca sacrificio. En caso de que él quiera viajar, él debe consultar Ifá antes de salir. Él debe ir si y sólo Ifá le pide que vaya.

Opón bémbé el sacerdote de la casa de Alara,
Àyìnbò, el sacerdote de la luna creciente
Adivinación lanzada para la luna creciente
Adivinación lanzada para un incontable de creyentes Musulmanes
En el día que ellos iban a la casa de Olódùmarè
El lugar que ellos llaman La Meca
Incontable número de creyentes Musulmanes iba a la casa de Olódùmarè
Cuando ellos viajan allí
Cuando ellos estarían regresando
La mitad de ellos se habría muerto
Ellos se pusieron asustados entonces de ir para la peregrinación
Ellos fueron rápidamente a Òrúnmìlà
'La casa de Olódùmarè que nosotros siempre visitamos'
'¿Cómo nosotros regresaríamos sin grabar (registrar, anotar) cualquier muerte?'
'Permita a La Meca convocar a usted', Òrúnmìlà contestó
'Quienquiera que está limpio y está a punto de seguir la peregrinación'
'Permita a La Meca llamar tal a una persona'
'Pero el resto de usted podría formar un grupo aquí'
Ésta es la raíz de formar la palabra 'Yídì'
Òrúnmìlà les pidió que trajeran un carnero
Y también para traer las hojas de odán
Ellos deben formar un grupo aquí en su morada
Ellos empezaron la agrupación de ellos en Yídì
'Usted debe estar teniendo su propia oración allí'
'Está allí que usted sabría quienquiera que sea llamado por Olódùmarè, Òrúnmìlà concluyó
Ellos empezaron haciendo así
Ellos estaban aumentando en número
Ellos empezaron a bailar y regocijar entonces
Ellos estaban alabando sus Babaláwos
Sus Babaláwos estaban alabando Ifá
Ellos dijeron que era como sus Babaláwos habían dicho
Opón bémbé, el sacerdote de la casa de Alara,
Àyìnbò, el sacerdote de la luna creciente lanzo adivinación creciente para la luna creciente
Ellos son unos que lanzan adivinación para incontable de creyentes Musulmanes
En el día ellos que iban a la casa de Olódùmarè
Ellos habían ido sin volver por completo
Ifá les pidió que se quedaran en casa para orar por su propio
Ilé mòmò yá o
Esta oración en casa es bueno
Es lo que todos llamamos 'Iléyá'

Òkànràn Òtúrúpòn B
Ifá pé àwon eléyìun ò gbodò bú àwon musulumi o. Ifá náà ni ón n sìn.

Lábirinkítí pi; Lábìrìnkìtì pi
Lábìrìn pìí pìí pèlú
A díá fún èìnlójo Ìmòle
Níjó tí ón làwon ò sin Ifá mó
Èìnlójo Ìmòle ló làwon ò sin Ifá mó
Ifá ní sé e ní e ò sin òun mó
Hain
‘Èèkan lèé mórí balè fún mi’
‘Sùgbón àìmoye ìgbà léé móo forí balè’
‘Léé móo fìdí balè’
Nnkankan náà là n sìn
Enìkan ò rídìí Òlódùmarè ju enìkan lo
Ifá lóun ò bínú píntín
Lábirinkítí pi; Lábìrìnkìtì pi
Lábìrìn pìí pìí pèlú
A díá fún èìnlójo Ìmòle
Níjó tí ón làwon ò sin Ifá mó
Ifá léé móo sìn
Àtorí o; àtìdì o léé móo fi sin òun
Àwá n sìn ó o
Lábirinkítí pi; Làbìrìnkìtì pi
Lábirinkítí pi; Làbìrìnkìtì pi
Èìnlójo ìmòle
Se bée léyìn ò sin Ifá mó?

Òkànràn Òtúrúpòn B
Ifá le pide a esta persona que no abuse de cualquier Musulmán. Ellos también le están rindiendo culto a Ifá

Lábirinkítí pi; Lábìrìnkìtì pi
Así hice Labìrìn pìí pìí
Adivinación lanzada para incontable numero de creyentes musulmanas
En el día que ellos renunciaron su fe en Ifá
Un grupo de Musulmanes incontable había renunciado su fe en Ifá
'Todos dijeron que ustedes no me rendiría culto de nuevo', Ifá dijo
'Eso es correcto
Usted sólo toca una vez su cabeza con la tierra para mí'
'Pero usted lo tocará ahora con el número incontable de veces
'Y también sus nalgas
'Nosotros somos los adoradores (fieles) del mismo Dios'
'Nadie puede demostrar él saber los secretos de Dios más que otro'
Ifá dice que él no está enfadado
Lábirinkítí pi; Lábìrìnkìtì pi
Labìrìn pìí pìí
Adivinación lanzada para incontable numero de creyentes musulmanes
En el día que ellos renunciaron su fe en Ifá
Es Ifá que usted sería adorador (fiel)
'Ambos con su cabeza y nalgas, usted me rendirá culto', Ifá dijo
Nosotros somos los adoradores de usted
Lábirinkítí pi; Lábìrìnkìtì pi
Lábirinkítí pi Lábìrìnkìtì pi
Incontable de creyentes musulmanes
¿Usted no dijo que usted no rendirá culto a Ifá de nuevo?

Òkànràn Òtúá A
Ifá pé kí eléyìn ó rúbo enu è. Enu ni gbogbo wa n bo; kó se ìmu. Ifá pé tó bá tójú àwon èèyàn, ti ón se àdúà fun, gbobo è ní ó rò ó.

Òkànràn túa tùa
Babaláwo Enu ló díá fún Enu
Enu ní n sawoó re Agbaa Ègbòo Fè Olúkiribítí
Enú bá dé Agbaa Ègbòo Fè
Wón bá tójú Enu
Tée don
Enu là n bo
Òòsà lenu
Enu nìbo rú
Enu nìbo yè
Bí ón se oúnje sílè
Enu ní ó je é
Bí ón se ohun múmu
Enu náà ní ó je é
Enú je, Enú mu tán
Ní bá n sàdúà
Iré bá dé
Ni wón wá n jó ni wón n yò
Wón n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè ni Babaláwo tòún wí
Òkànràn túa tùa
Babaláwo Enu ló díá fún Enu
Enu ní n sawoó re Agbaa Ègbòo Fè Olúkiribítí
Enu mòmò lEgúngún o
Enu mòmò lÒrìsà
Enu ni wón n bo lóótù Ifè
Táyé fí n dára
Ejé á rójú ká móo bo enu
Enu mòmò lÒrò

Òkànràn Òtúá A
Ifá le pide a esta persona que ofrezca sacrificio hacia la boca. Él debe preparar comida y bebidas para entretener a las personas. Ifá dice si él podría hacer esto y ellos oran para él, sus cosas estarán bien.

Òkànràn túa tùa
El Babaláwo de la Boca lanza adivinación para la Boca
La Boca estaba aventurando sacerdocio en Àgbá Ègbò Ifè Olúkiribítí
Cuando la Boca llegó a la ciudad
Ellos lo entretuvieron
Hasta la fecha
Todos nosotros estamos ofreciendo sacrificio a la Boca
Porque la Boca es una Deidad
La boca es el blanco de aceptabilidad de sacrificios
Es el único a sacrificar para supervivencia
Si ellos cocinan cualquier comida
Es la Boca que lo comería
Si ellos preparan cualquier bebida comida
Es la Boca que lo consumiría
La Boca terminó comiendo y bebiendo
Y empezó orando
Y las cosas buenas vinieron
Ellos empezaron a bailar y regocijar entonces
Ellos estaban alabando su Babaláwo
Su Babaláwo estaba alabando Ifá
Ellos dijeron que era como su Babaláwo había predicho
Òkànràn túa tùa
El Babaláwo de la Boca lanza adivinación para la Boca
La Boca estaba aventurando sacerdocio en Àgbá Ègbò Ifè Olúkiribítí
La Boca es la Mascarada
La Boca es el Òrìsà
Es la Boca que ellos están ofreciendo los sacrificios en la ciudad de Ifè
Eso está haciendo la vida habitablemente mejor
Permítanos intentar ofrecer sacrificios a la Boca
La Boca es la palabra.

Òkànràn Òtúá B
Ifá pé àwon Elénìní ó móo fé te eléyìun; wón ó móo fé tè é rì; Iró ni. Eléyìun ó jayé dé ibí ó féé jayé dé. Ifá pé òpòlopò òòrí ni kí eléyìun ó fi kún ebo rú. Kí eléyìun ó sì pon omi kún inúu kèngbè kan kí wón ó lòó gbé e sí ìdí Èsù. Kí wón ó fi òòrí ra kèngbè òhún nínú kí wón ó tó fi pon omi.

Òkànràn túú túú
Babaláwo Kèngbè ló díá fún Kèngbè
Níjó ti n lo sí Ogún ìlémi
Kèngbè ní n lo sógun Ìlémi
Wón ní ó rúbo
Wón ní kó rú òòrí
Wón ní kó fi òòrí òhún ra inú è
Kèngbé bá rúbo
Ngbà ti ón dé ogun Ìlémi
Bí ón ti n ti Kèngbè bo inú omi
Ní n jáde padà
Gbogbo àwon yòókù ni ón rì
Béèyàn pon omi kún inú è
Kèngbè ó jáde padà sókè ni
Ní wá n jó n ní n yò
Ní n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó béè làwon Babaláwo tòún wí
Òkànràn túú túú
Babalwo Kèngbè ló díá fún Kèngbè
Níjó tí n lo sí Ogun Ìlémi
A rúbo nígbà yí a según
Akèrèngbè
A según lóde Ìlémi
Akèrèngè

Òkànràn Òtúá B
Ifá dice que algunos detractores intentarían suprimir a esta persona. Esto no sería posible; Él se destina para disfrutar máximamente la vida. Deben agregarse mantecas cacao a su sacrificio. Él también debe llenar una calabaza de agua y debe ponerlo al lado del lugar de Èsù. El interior de la calabaza debe untarse con la manteca de cacao (Shea butter).

Òkànràn túú túú
El Babaláwo de la Calabaza lanza adivinación para la Calabaza
En el día que él iba a la guerra de Ìlémi
La Calabaza iba a la guerra de Ìlémi
Ellos le pidieron que realizara sacrificio
Ellos le pidieron que sacrificara manteca de cacao
Y debe frotarlo en su interior
La Calabaza realizó el sacrificio
Cuando ellos llegaron a la guerra de Ìlémi
Cuando ellos estaban intentando sumergir la Calabaza en agua
Él estaba saliendo
Todos los otros hundieron
Si uno llena una Calabaza de agua en un arroyo
La calabaza nunca sumergiría
Él empezó a bailar y regocijar entonces
Él estaba alabando su Babaláwo
Su Babaláwo estaba alabando Ifá
Él dijo que era exactamente lo que su Babaláwo dijo
Òkànràn túú túú
El Babaláwo de la Calabaza lanza adivinación para la Calabaza
En el día que él iba a la guerra de Ìlémi
Nosotros hemos realizado sacrificio y habíamos ganado
Akèrè`ngbè
Nosotros hemos ganado la guerra de Ìlémi
Akèrè`ngbè.


Òkànràn Ìretè A
Ifá pé ká rúbo; nnkan eni ò níí bàjé. Ifá pé omo Awo leni ó wá dá Ifá yìí. Owó ayé ò níí tè é, àti pé lóríi rere tó féé se, ebo ayé ni kó rú kí owóo rè ó lè tere. Nnkan kan n be tí ón rò pé eléyìun ò níí gbóngbón mò; ó wáá mo nnkan òhún ni ón fé móo dà á láàmú sí. Won ò níí lè mú u. Ebo kí wón ó mo lè mú u ni kó rú. Ení ó bá lóun ó se eléyìun, wón ó se araa won.

Amépo mépo aloré
A díá fún Irú tíí somo Òrúnmìlà
Irù wáá gbón pupo
Ó rúbo
Oyè ilée baba è
Ó je é
Gbogbo ohun ti ón rò pé ò níí gbón gbón mò
Ó mò ó
Ayé ye é
Nnkan è ò bàjé
Ó rójú ó ráyè
Ní wá n jó n ní n yò
Ní n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Amépo mépo aloré
A díá fún Irù tíí somo Òrúnmìlà
Wón ní ó sá káalè ebo ní ó se
Irù gbébo nbè, ó rúbo
Bée péé pa Irù
Araa yín le pa
Èèyàn è é pa Irù omo Èdú
Be bá péé pa Irú
Araa yín le pa

Òkànràn Ìretè A
Ifá le pide a esta persona que realice sacrificio. Sus cosas no se estropearian. Ifá dice que esta persona es el niño del Babaláwo. Sus enemigos terrenales no lo arrestarían. Él debe ofrecer sacrificio para sus manos tocar las cosas buenas que él tiene en la mente. Hay una cosa particular que sus enemigos piensan que él no sabría; Él consigue saber las cosas y ésta es la fuente del problema que él está encontrando. Ellos no podrían arrestarlo.

Amépo ,épo aloré
Adivinación lanzada para Irù, el niño de Òrúnmìlà
Irù es muy inteligente
Él también había realizado el sacrificio
El banquillo (taburete) de su padre que era libre,
Él lo ascendió
Todas las cosas que ellos pensaron que él no sería sabio bastante para saber
Él lo conoció
La vida lo agradó
Sus cosas no se estropearon
Él llego a tiempo y espacio para hacer las cosas
Él empezó a bailar y regocijar entonces
Él estaba alabando su Babaláwo
Su Babaláwo estaba alabando Ifá
Él dijo que era exactamente como su Babaláwo había dicho
Amépo mépo aloré
Adivinación lanzada para Irù, el niño de Òrúnmìlà
Le pidieron cuidar de la tierra y realizar el sacrificio
Irù oyó hablar del sacrificio y lo realizó
Si usted dice que usted matará Irù
Usted se pegará sólo
Nadie puede matar Irù el niño de Èdú
Si usted dice que usted matará Irù
Usted se pegará sólo

Òkànràn Ìretè B
Ebo ni kí eléyìun ó rú. Ifá póun ó ba ségun òtá; bénìkan bá gbógun tì í, eléyìun á dá ra è lébi.

Eérú inú Ilé ní n fónká i yángá, i yángá
Èéfíin rè a kè riri, ké bebe
Alábahun méjì ni wón n jà lókè
Ni wón n hán araa won pákó pàkò pákó
Enìkan ò leè ménìkan
Enìkan ò leè dénìkan
A díá fún Etu àti Èkìrì
Níjó tí wón n bá Ikin sòtá
Wón ní kí Òrúnmìlà ó rúbo
Kó lè baà ségun àwon méjèèjì
Òtá Òrúnmìlà ni Etu àti Èkìrì
Wón gbógun ti Òrúnmìlà
Òrúnmìlà ò dún
Kò gbin
Òrúnmìlà bá rúbo
Àwon Etu àti Èkìrì bá sá lo
Wón ho lo inú igbó
Nígbà dijó kan
Ògún bá n re Igbó méje èlùjù méje
Ògún bá wá sódò Òrúnmìlà
Odò Òrúnmìlà lÒgún tíí móo dira ìgbé
Yóó rúbo
Òun ò rija eranko?
Ó dáa fún òun?
Erán kú?
Èèyàn yè?
Ayé ye òun?
Okán òún balè?
Òún nísinmi?
Wón níwo Ògún rúbo
Òrúnmìlà ní Etu leboò re
Èkìrì leboò re!
Etu àti Èkìrì sì ti sá wo inú igbó lo
Bí Ògún ti dé inú igbó
Etu ló kókó rí
Ó di pèrè
Ó yì ín níbon
Etú kú
Ó rí Èkìrì
Ó tún di pèrè
Ó yì ín níbon
Èkìrì kú
Ló bá kó gbogbo è wá fún Òrúnmìlà
Òrúnmìlà bá fi Awo àwon méjèèjì kan ìlù
Ifá póun ó bàá eléyìun ségun
Eérú inú Ilé ní n fónká i yángá, i yángá
Èéfíin rè a kè riri, kè bebe
Alábahun méjì ni wón n jà lókè
Ni wón n hán araa won pákó pàkò pákó
Enìkan ò leè ménìkan
Enìkan ò leè dénìkan
A díá fún Etu àti Èkìrì níjó ti wón n bá Ikin sota
Ifá epé awoo wón ti dìpèsè
Àti Etu ni
Àti Èkìrì ni
Ti n bá Ikin sòtá
Awoo wón sì ti dìpèsè.

Òkànràn Ìretè B
Esta persona debe realizar sacrificio. Ifá dice que él le ayudaría a ganar a sus enemigos. Si cualquiera guerrea contra él, la otra persona lo sentiría.

Son las cenizas en la casa que salpica
El polvo undularía extendiendo por todas partes
Dos tortugas comprometen en una lucha
Besándo una a la otra
Uno es incapaz ganar al otro
Adivinación lanzada para Etu y Èkìrì
En el día que ellos comprometieron en la guerra con Ikin
Ellos le dijeron a Òrúnmìlà que ofreciera sacrificio
Tal que él pudiera ganar a los dos de ellos
Etu y Èkìrì eran enemigos jurados de Òrúnmìlà
Ellos comprometieron Òrúnmìlà en la guerra fría
Òrúnmìlà no los molestó
Él no les contestó
Él realizó el sacrificio
Etu y Èkìrì corrieron lejos después de un rato
Ellos se encontraron dentro de los bosques
En un día fatal
Ògún iba a siete bosques renombrados y arbustos
Él vino a encontrarse a Òrúnmìlà
Correcto del ataque, Ògún siempre preparan para cazar primero de presas para la adivinación
Él habría observado todos sus sacrificios
'¿Yo no encontraría la guerra animal?'
'¿Sería bueno para mí?'
'¿Las presas morirían?
'¿El ser humano sobrevive?'
'¿La vida me agrada?'
'¿Yo tendría descanso de mente?'
'Yo tendría paz? Ògún siempre preguntaría
'Realice el sacrificio Ògún, Òrúnmìlà contestó
¡Su sacrificio principal es Etu!
¡Y el segundo es Èkìrì!
Entretanto Etu y Èkìrì habían corrido lejos, en los bosques espesos
Inmediatamente Ògún entró en el bosque
Él vio Etu primero
Con una explosión fuerte
Él disparó a ella
Etu se murió
Él vio otra explosión fuerte
Él grito a ella también
Èkìrì también se murió
Él los trajo para Òrúnmìlà
Òrúnmìlà usó sus pieles entonces para hacer los tambores
Ifá dice que él ayudaría esta victoria de la persona
Son las cenizas en la casa que salpica
El polvo produce brillo mientras extendiendo por todas partes
Dos tortugas comprometen en una lucha
Uno es incapaz de ganar el otro
Uno es incapaz enlosar (embaldosar, enladrillar) el otro
Adivinación lanzada para Etu y Èkìrì, en el día que ellos comprometieron en la guerra con Ikin
Ifá dice que sus pieles se habían convertido para el sacrificio
Sea Etu
Sea Èkìrì
Aquéllos que son belicosos contra Ikin
Sus pieles se habían convertido para el sacrificio

Òkànràn Òsé A
Ifá pé kí eléyìun ó lòó bo Òsun. Ayé ó ye é. Ifá pé kó mó jà o.

Bísèé bá n se won
Èrín ni wóón rín
Òtòsì ó féhun mìíìn
Bíi ká jí ká móo rínraa wa
A díá fún Òsun Ògèlèngèsé
Èyí ti n regbó Ìrágbìjí
Ti n lo rèé rawó rasè ntorí omo
Òsun Ògèlèngèsé nìí
Òún bímo báyìí?
Wón níwo Òsun
Omoò ré pò
Ó ó lénìsìn láyé
Òsun bá rúbo
Ó dé igbó Ìrágbìjí
Ààyé bá gba Òsun
Ló bá kalè nbè
Ayé bá ye é
Ní wa n jó n ní n yò
Ní n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo náà n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Bísèé bá n se won
Èrín ni won rín
Òtòsì ó féhun mìíìn
Bíi ká jí ká móo rínraa wa
A díá fún Òsun Ògèlèngèsé
Èyí ti n regbó Ìrágbìjí
Ti n lo rèé rawó rasè ntorí omo
Kín làá bo níbè tó bá bí ni?
Òsun òtòòròèfòn
Làá bo níbè bó bá bí ni
Òsun òtòòròèfòn

Òkànràn Òsé A
Ifá le pide a esta persona ir y ser un devoto de Òsun. La vida lo agradaría. Ifá lo manda no guardar la malicia.

Si ellos se afligen por la pobreza
Ellos se reirían sobre esto
Una persona infeliz no quiere nada más
De otra que despierta y está riéndose de la desgracia de otras personas
Adivinación lanzada para Òsun Ògèlèngèsé
Una que iba a los bosques de Ìrábgìjí
Que iba a orar debido a niños
Aquí es Òsun Ògèlèngèsé
¿Ella estaba preguntándole a Ifá 'yo tendría los niños?'
Usted Òsun, ellos le contestaron
Usted tendrá tantos niños
Usted tendrá devotos incluso en la vida
Òsun realizó el sacrificio
Ella llego a los bosques de Ìjágbìjí
Ella tenía mucho espacio para ella
Ella se estableció allí
La vida la agradó así
Ella empezó a bailar y regocijar entonces
Ella estaba alabando su Babaláwo
Su Babaláwo estaba alabando Ifá
Ella dijo que era exactamente como su Babaláwo dijo
Si el se aflige por la pobreza
Ellos se reirían sobre esto
Una persona infeliz no quiere nada más
De otra que despierta y está riéndose de la desgracia de otras personas
Adivinación lanzada para Òsun Ògèlèngèsé
Una que iba a los bosques de Ìrágbìjí
Para orar debido a niños
¿Qué nosotros rendimos culto si uno nace por ella?
Òsun òtòòròèfòn!
Es lo que nosotros debemos rendir culto si uno nace por ella
Òsun òtòòròèfòn

Òkànràn Òsé B
Ifá pé kí eléyìun ó rúbo. Ó féé lo síbìkan; yóó donílè lóhùún. Yóó ju àwon tó bá nbè lo. Igbá funfun, eyelé, àti aso funfun lebo eléyìun. Kó dé eyelé kan mó inú igbá àdému funfun, kó sì lòó gbé e ka ese òkè kó le tóbi láyé. Eléyìun sún mó enìkan tó tóbi. Ifá pé yóó ju onítòhún lo; sùgbón kó rúbo.

Òkànràndàsénù
Awo Orí ló díá fún Orí
Orí ní n lo rèé bá won múlèe bùdo
Wón ní kí Orí ó rúbo
Òkànràndàsénù
Awo Òkè ló díá fún Òkè
Òkè n lòó bá won múlèe bùdo
Wón ní ó rúbo
Orí ati Òkè ní bò wá láti ìkòlé Òrun
Òkè ló kókó dé
Ló ti mé ilè
Òké ní kò sírú òun mó
Wón ní kí Orí ó rúbo
Wón ní yóó gorí Òkè
Orí bá rúbo
Eyelé tée rúbo
Wón gbé e ka ese òkè
Bí ón ti gbé eyelé ka ese òkè tán
Ló bá fò
Ó fo Òkè ru
Òkè tó ti ní kò séni tó le fo òun ru
Orí bá gbálè n bùdo
Òkè tó ti kókó múlè télè
Wón ò rántí è mó
Ó ní Òkànràndàsénù
Awo Orí ló díá fún Orí
Orí ní n lo rèé bá won múlèe bùdo
Wón ní kí Orí ó rúbo
Òkànràndàsénù
Awo òkè ló díá fún Òkè
Òkè n lòó bá won múlèe bùdo
Wón ní ó rúbo
Orí ló gbébo nbè
Ló wáá rúbo
Orí ló nilè níbùdo
Òkànràndàsénù Awo Orí
Orí ló nilè níbùdo

Òkànràn Òsé B
Ifá le pide a esta persona que realice sacrificio. Él quiere viajar a alguna parte; Ifá dice que él se volvería un residente del lugar. Él sería mayor que aquéllos que él se encontrará allí. La calabaza blanca, las palomas, lino blanco es el sacrificio. Ifá le pide que cubra una paloma en un blanco 'àdému' y ponerlo al lado de una colina. Ifá dice que él será un hombre poderoso. Hay una cierta personalidad importante al lugar que él está visitando. Ifá dice que esta persona lo eclipsaría.

Òkànrándèsénù
El Babaláwo de Orí lanza adivinación para Orí
Orí iba a escoger la tierra para él en un sitio
Ellos le dijeron que realizara sacrificio
Òkànrándèsénù
El Babaláwo de la Región montañosa (altiplano) lanza la adivinación para la Región montañosa
La Región montañosa iba a escoger una tierra para él en un sitio
Ellos le dijeron que realizara sacrificio
Orí y la Región montañosa estaban viniendo a la tierra
La Región montañosa consiguió primero a la tierra
Escogió un lugar bueno para residir
Él alardeó que ahí no podría haber nunca cualquiera que lo aventajara
Ellos le pidieron a Orí que ofreciera sacrificio
Ellos le aseguraron que él subiría encima de las colinas
Orí realizó el sacrificio
La Paloma que él usó como sacrificio
Se puso al lado de la Región montañosa
La Paloma llego al lado de la Región montañosa
Y salió volando
¡Voló encima de la Región montañosa!
La Región montañosa que había pensado que nadie podría llegar a su cima permitido sola volar encima del
Se establece Orí en el lado
La Región montañosa que escogió la tierra primero
No se recordó de nuevo
Él dijo Òkànrándèsénù
El Babaláwo de Orí lanzo adivinación para Orí
Orí iba a escoger la tierra para él en un sitio
Ellos le dijeron que realizara sacrificio
Òkànrándèsénù
El Babaláwo de la Región montañosa lanzó la adivinación para la Región montañosa
La Región montañosa iba a escoger la tierra para él
Ellos le dijeron que realizara el sacrificio
Orí es el que oyó hablar del sacrificio
Y lo realizó
Es Orí que tiene la tierra en el sitio
Òkànrándèsénù, el Babaláwo de Orí,
Es Orí que posee la tierra en el sitio (lugar)

Òkànràn Òfún A
Ifá pé eléyìun ò níí té láyé è. Èmí è ó gùn; ebo Iyì ni kó rú. Èfóo tètè nÍfá gbà. Kó kó àwon èèyàn jo, kó se èfóo Tètè, kó sì fi irú, iyò, àti epo sí i. Kí wá fi fún àwon èèyàn je. Ifá pé yóó nìíyì láyé è.

Ìyèròsùn abenu síìnrìsín
A díá fún Títílolá
Àrèmo Agbeni
Òun ò té láyé òun?
Títíítí òun ó fi lo ayé òun gbó
Wón ní ò níí té
Wón nírú ó níí té
Iyò ò níí té
Tètè è é sìí té láwòjo èfó
Wón ní ò níí té láíláí
Títílolá Àrèmo Agbení bá rúbo
Láyé bá ye Títílolá
Ní wá n jó n ní n yò
Ní n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo náà n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Ìyèròsùn abenu síìnrìnsín
A díá fún Títílolá
Èyí tíí sÀrèmo Agbeni
Wón ní ó sá káalè ebo ní ó se
Ebo kó mó baà té nle ayé ni ón ní ó se
Títílolá gbébo nbè ó rúbo
Irú è é té o
Iyò è é té o
Tètè è é té láwùjo èfó
Ifá dákun má sì jé n té láíláí

Òkànràn Òfún A
Esta persona no se ridiculizaría. Él tendría la vida larga; Él debe ofrecer sacrificio para la afluencia (abundancia, riqueza). Ifá colecciona la verdura (legumbre) de Tètè de él. Él debe congregar a las personas y debe entretenerlos con la sopa de verdura deTètè. Él debe agregar sal, fríjol de algarrobo (acacia, cigarra, langosta, saltamontes) [locust bean] y aceite. Él sería influyente en la vida.

Ìyèròsùn abenu síìnrìnsín
Adivinación lanzada para Títílolá
El mayor niño de Agbeni
¿Yo no me ridiculizaría?
¿El resto de mi vida estaría bien?
Ellos lo aseguraron que él no se ridiculizaría
Ellos dijeron que el fríjol de algarrobo (acacia, cigarra, langosta, saltamontes) [locust bean] nunca se ridiculizaría
La Sal nunca se ridiculizará
La verdura de Tètè nunca se ridiculizaría en medio de las compatriotas verduras
Ellos lo aseguraron que él nunca se ridiculizaría
Títílolá realizó el sacrificio
La vida agradó Títílolá
Él empezó a bailar y regocijar entonces
Él estaba alabando su Babaláwo
Su Babaláwo estaba alabando Ifá
Él dijo que era como su Babaláwo había dicho
Ìyèròsùn abenu síìnrìnsín
Adivinación lanzada para Agbeni
Le pidieron que cuidara de la tierra y realizara sacrificio
Tal que él no se ridiculizaría
Títílolá oyó hablar del sacrificio y lo realizó
La mantequilla de fríjol algarrobo (acacia, cigarra, langosta, saltamontes) [locust bean] nunca se humillará
La sal nunca se ridiculizará
La verdura de Tètè nunca será se mofaría en medio de las verduras
Ifá, por favor, nunca me permita burla en la vida.

Òkànràn Òfún B
Ifá pé kí eléyìun ó rúbo. Tó bá se Obìnrin ló dá Ifá yóó fi pátá ìdí è rúbo; bó sì se Okùnrin ni, sòkòtò è ní ó fi rúbo. Ifá póun ò níí jé kí eléyìun ó rí àárè. Yóó lo Ilé ayé è kodoro.

È ra bójó bójó
È ta pónhún pónhún
A díá fún Dùùrù
Níjó ti n gbóguún re ilèe Lìkì
Wón ní ó rúbo
Dùùrú rúbo
Wón gbógun tìí títí
Won ò ségun è
Kò séni ó borí è
Dùùrú kàn n ta kónbó ni
Ayé ye é
Ní wá n jó n ní n yò
Ní n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
È ra bójó bójó
È ta pónhún pónhún
A díá fún Dùùrù
Níjó ti n gbóguún re ilèe Lìkì
Wón ní ó yáa rúbo
Dùùrú gbébo nbè ó rúbo
Mo mò sebo èra bójó bójó; è tá pónhún pónhún
È ra bójó bójó; è ta pónhún pónhún

Òkànràn Òfún B
Ifá le pide a esta persona que ofrezca sacrificio bien. Si es una mujer, ella debe sacrificar sus pantalones [pants: pantalones, calzones]; si él un hombre, él usaría un par de pantalones. Ifá dice que él no conocería enfermedad. Él disfrutaría la vida al fin.

È ra bójó bójó
È ta póhún póhún
Adivinación lanzada para la guitarra del Piano Local
En el día que él era belicoso en la tierra de Lìkì
Le pidieron que realizara sacrificio
La Guitarra realizó el sacrificio
Ellos guerrearon y guerrearon contra él
Ellos no podrían superarlo
La Guitarra simplemente era demasiado saludable y rebosado con vitalidad
La vida lo agradó así
Él estaba bailando entonces y estaba regocijando
Él estaba alabando su Babaláwo
Su Babaláwo estaba alabando Ifá
Él dijo que era exactamente como su Babaláwo había dicho
È ra bójó bójó
È ta pónhún pónhún
Adivinación lanzada para la guitarra del Piano Local
En el día que él era belicoso en la tierra de Lìkì
Le pidieron que realizara sacrificio rápidamente
La Guitarra del Piano oyó hablar del sacrificio y lo realizó
Yo he realizado el sacrificio de Èra bójó bójó; È ta pónhún pónhún
È ra bójó bójó; È ta pónhún pónhún


Las Palabras Difíciles
Òkànràn

1. Kèèròmí: El nombre de un Babaláwo. El nombre se traduce a 'no es todavía fácil para mí'
2. Ologun Ìsesè: El nombre de un lugar y posiblemente una persona
3. Iyùn: Un tipo de cuenta Cara. Ámbar en color
4. Idè: Un cordón de muerto atado por Babaláwos y reconocido con Ifá
5. Ògúnsèrè: Un árbol con las hojas anchas apropiado por envolver las comidas en la tierra Yorùbá
6. Eléko: 'Èko' es el flan (natilla) duro. Y la persona que lo prepara es un Eléko
7. Olóriri: Casi el mismo significado con Èko. Pero orriri sólo es más grande
8. Ruwan yaa so ruman sanmo: Los dos son palabras de Hausa de apropiarse en Yorùbá. Traduce la Lluvia ha venido", La lluvia del cielo
9. Yangí aborí Kugú: El nombre de un Babaláwo
10. Òkàn kì kìì kì: El nombre de un Babaláwo. Nota que ki kii ki. cuando el sonido hecho por las gotas de lluvia cuando está a punto de llover.
11. Ma rín o Kú ma sá: El nombre de un Babaláwo. Esto puede traducirse a 'yo me reí de usted y su muerte, yo correré lejos'
12. Ma sá o kú ma rín: También un nombre de un Babaláwo. También traduce 'Si yo corro y usted se murió. Yo me reiría de usted'
13. Yànnbílíkí o kú yan páàsì: El nombre de un Babaláwo. Significando inseguro
14. Òyó: Una ciudad en la parte sudoeste de Nigeria
15. Igún: El buitre. También Gúnnugún
16. Tèntèré: Un tipo de pájaro
17. Òsìn: Atra clase de pájaro
18. Àkodá
Asèdá
Olúwo Los títulos de jefes en Ifá
Odùgbònà
Àgbongbòn
19. Òkànràn Din-din-kúù-din-kúùn-din: El tono hecho por el molde cuando está usándose para formar un metal
20. Koko: El tono alto producido por el tambor de bátà. También el nombre de la esposa de Sàngó
21. Bàtá se ponía de pie: Una indicación para decir sobre el aumento en el volumen, diapasón y paso de ritmo del golpe de tambor cuando el espíritu es alto
22. Olúbámbí: Otra de las muchas denominación para Sàngó
23. Omo Olórun tó figbá bo ìwà mole: Un nombre de frase (expresión, modismo). El niño de Dios que había cubierto (tapado) el carácter con la calabaza
24. Àlá Òru: Las pesadillas
25. A Yín Gínní gínní bomo lénu: Traduccion al que corta pedazos de comida en la boca de un bebé
26. Yídí: La tierra de oración musulmana. Éste es un nombre que sale de frase Yoruba 'E yí dì'. Esto se traduce a 'forma un grupo aquí'. Ésta es otra prueba para mostrar que todos los nombres y fraces Yoruba realmenten vienen fuera de Ifá. El mismo va para. Ileya, llos Muslimanes Id el Kabir. Qué está fuera de la palabra Yoruba el "Ilé ti yá', o 'es tiempo para ir a casa.'
27. Lábirinkítípi: Esto describe la manera por que los musulmanes usan su cabeza para tocar la tierra y casi sentándose en una caída (desplome, derrumbe).
28. Òkànràn túa túa: El nombre de un Babaláwo. También Òkànràn túú túú
29. Ìlémi: Un proverbial del pueblo derivado de dos formula Ilé y Omi. Omi es el agua; y el anterior es un verbo y cláusula del nombre que traducen al acto de flotar y los dos podrían unirse para significar el acto de flotar en el agua. Esto describe la manera por que la calabaza flota en el agua.
30. Amépo mépo aloré: El nombre de un Babaláwo
31. Irù: La mosca tsetse
32. Usted se golpeará: La mosca tsetse es muy rápida y su reflejo es muy afilado. Cualquier esfuerzo por el hombre por matar la mosca mientras esta chupando sangre pegándole en esa sitio produciría un esfuerzo en la futileza (inutil); porque la mosca tendría volar fuera de esa sitio antes la palmada mortal aterrice (de) en ella. Haciendo, el hombre para manotearse.
33. Etu y Èkìrì: La caza (Games: Caza (deportiva), Juejos) en el bosque
34. Òsun Ògèlèngèsé: La deidad de Òsun. También llamada Òtòòròèfòn.
35. Ìrágbìjí: La montaña / la ciudad de dónde surgen los ríos de Òsun.
36. Òkànràn dàsénù: Otro nombre para Òkànràn Òsé. El nombre de un Babaláwo. Pero (Lt) traduce a Òkànràn tira la pobreza
37. Ìyèròsùn: El polvo de Ifá
38. Tíílolá: El nombre de una persona. Los medios 'nuestras riquezas serían continuas'
39. Agbeni: El nombre de un lugar en la tierra Yoruba. (Lt) El uno, o la cosa que muestra el favor a uno.
40. Èra bójó bójó y èta pónhún: Notas dadas por la guitarra cuando la mano la golpea. El nombre del Babaláwo de la guitarra local.
41. Sánáá ní: Para comportarse negligentemente a alguien o a una situación particular.
42. Jìngbìnní: El nombre de uno de las esposas de Òrúnmìlà
43. Ilé Ètilè: El nombre de una ciudad antigua dónde Òkànràn méjì fue lanzado primero. Como resultado de ser su Ifá soltero, él se proveyó de comida bien para y se hizo rico. Así su no deseo de devolver casa.




No comments:

Post a Comment